Aarẹ Amẹrika tuntun: Wọn tun fẹẹ ko ba wa ni Naijiria

Afi bii igba ti wọn ran ọkunrin naa sita pe ko waa daamu aye. Donald Trump, Aarẹ Amẹrika ti wọn ṣẹṣẹ fi ibo yọ ni. O ti lo ọdun mẹrin o, ọdun mẹrin mi-in lo n beere fun, ko le jẹ saa keji ti yoo lo, nitori bi gbogbo aarẹ Amẹrika ti n ṣe niyẹn. O ti fẹẹ pe ọdun mẹẹẹdọgbọn bayii ti aarẹ kan ti jẹ ti ko lo saa meji, Trump lo tun tẹle e, ọkan ninu awọn aarẹ Amẹrika diẹ ti yoo wa lori oye ti wọn yoo fibo yọ danu ni! Ọkunrin naa ja raburabu, koda o da kinni naa sagidi, bi ko si jẹ ijọba tiwa-n-tiwa ti wọn n pe ni dẹmokiresi fẹsẹ mulẹ daadaa ni Amẹrika yii ni, ọkunrin Trump yii iba ba nnkan jẹ fun wọn. Bi inu ile kan ba n toro, ọmọ ale ibẹ ni ko ti i dagba, nitori gbogbo ọjọ aye ni awọn ọmọ Amẹrika fi maa n fọnnu pe ko si dẹmokiresi to dara bii tiwọn ni gbogbo aye, ṣugbọn diẹ lo ku ki Trump ba kinni ọhun jẹ, nitori niṣe lo sọ Amẹrika ọhun di yẹpẹrẹ loju aye gbogbo.

Lara ohun ti Amẹrika fi n gbera, to si fi n niyi loju aye gbogbo ni pe ko si ẹlẹyamẹya nibẹ, bo ba si wa, ko to nnkan rara ni. Bi Kristẹni ti pọ, bẹẹ ni Musulumi wa, bi eeyan dudu ti n bẹ, bẹẹ ni awọn funfun pọ rẹpẹtẹ, bi eeyan ba si ti di ọmọ Amẹrika, ko sẹni ti yoo tun pitan aburu fun un, tabi itan pe ki i ṣe ọmọ oniluu, pe ko pada sibi to ti wa. Aye Trump ni nnkan yipada biri, ti gbogbo awọn ti wọn ti n ri Amẹrika bii ile wọn di ajoji nibẹ lẹẹkan naa, nitori ijọba Trump jẹ ko ye wọn pe alejo ni wọn, alejo ni awọn eeyan dudu nibẹ, awọn ti awọn jẹ funfun lawọn ni ilu awọn, ko si si ohun ti ẹnikẹni le ṣe si i, ẹni ti ko ba tẹ lọrun ko gba ilẹ baba ẹ lọ. Ọrọ naa ṣajoji loju araye gbogbo. Paripari rẹ ni pe o kọju ija sawọn Musulumi, ọrọ naa si fẹrẹ pin aye si meji. Ni gbogbo aye ba n pariwo pe awọn ko ma ri iru eleyii ri o.

Bẹẹ awọn eeyan naa ni ko fura o, nitori ko too wọle, lasiko ti wọn n ṣe kampeeni ibo ni 2015, lo ti fihan pe ijọba ẹlẹyamẹya ni oun yoo ṣe. Lati igba naa lo ti fi i han pe oun koriira awọn eeyan dudu, bo ba si ṣee ṣe foun, oun ko fẹ wọn ni Amẹrika rara. Bakan naa lo ṣe fawọn Musulumi, nitori ni ọjọ keje, oṣu kejila, ọdun 2015 yii, lo ti sọ nibi kampeeni ẹ kan pe ti oun ba fi le wọle o, oun yoo kọkọ ni ki awọn Musulumi gbogbo jokoo siluu wọn, tit ti awọn aṣofin yoo fi mọ ohun ti wọn yoo ṣe si ọrọ wọn, boya ki wọn ma wọ Amẹrika mọ ni o, tabi ki awọn ti wọn wa nibẹ paapaa maa lọ. Ni gbogbo aye ba pariwo, awọn kan si dide ni Amẹrika nibẹ pe iru ọrọ bẹẹ ko yẹ ko tẹnu ẹni to fẹẹ di aarẹ ilẹ Amẹrika jade, nitori Amẹrika yii, ti gbogbo aye ni, ko si si ọmọ oniluu kan ti wọn le jade nibẹ ri, afi ọdaran nikan.

Ki i ṣe eleyii nikan lo sọ, Trump bẹrẹ si i ṣalaye pe awọn alawọ-dudu ko ṣee fi we alawọ-funfun, nitori ni gbogbo ọna ni awọn ti awọn jẹ alawọ-funfun fi ju dudu lọ, bo jẹ ti ka ronu ọpọlọ ni o, tabi ki eeyan le ṣe ohun to yẹ ko ṣe lasiko, tabi nipa idagbasoke ilu tabi agbegbe ni, ko si ibi kan ni gbogbo aye ti eeyan ti le fi alawọ-funfun we alawọ-dudu, o ni awọn ki i ṣẹgbẹ wọn rara ni. O ni ni Amẹrika paapaa, awọn alawọ-dudu ti wọn wa nibẹ kan n ṣe ẹrusin fun awọn funfun ni, nitori ko si laakaye ti wọn le fi ṣe ohun ti awọn funfun n ṣe ni agbari wọn. O ni ki awọn alawọ-funfun Amẹrika mọ pe awọn lawọn ni ilu awọn o, ki wọn si mura lati gba nnkan wọn lọwọ awọn dudu, nibi yoowu ti wọn ba ti ri eeyan dudu kan to fẹẹ jẹ gaba lori wọn. Ni ti Donald Trump, alawọ-funfun lo gbọdọ maa ṣọga awọn alawọ-dudu.

Bi Trump ti n sọ awọn ọrọ buruku yii, bẹẹ lawọn eeyan n pa a lẹnu mọ, wọn si n sọ fun un pe ọrọ ẹlẹyamẹya to n sọ yii, ohun to le da wahala silẹ ni Amẹrika ni. Ṣugbọn kinni naa ti wa ninu ẹjẹ ọkunrin Trump yii, nitori bo ba sọ pe oun gbọ loni-in yii, bo ba tun dọla, yoo tun sọrọ mi-in ti yoo jọ eyi to ti sọ lakọọkọ ni. Ohun to waa ṣẹlẹ ni pe bi awọn kan ti n bu u yii, ti wọn n sọ pe ọrọ to n sọ ko dara, lati igba naa ni awọn kan ti bẹrẹ si i fẹran rẹ, iyẹn awọn oyinbo alawọ-funfun ti wọn fẹran ẹlẹyamẹya nibẹ, awọn ti wọn ko fẹ awọn alawọ-dudu lọdọ wọn, ṣugbọn to jẹ ko si ohun ti wọn le ṣe ni, ti wọn ko si le sọrọ naa sita pẹlu. Awọn yii ti n mu kinni naa mọra lati ọjọ to pẹ, awọn ti wọn gbagbọ pe olooorun leeyan dudu, ati awọn mi-in ti wọn gbagbọ pe ko yẹ ki wọn wa lawujọ awọn ti awọn jẹ alawọ funfun.

Kamala Harris, igbakeji Biden

Kia ni awọn yii bẹrẹ si i pọ niye, ti wọn si n gbilẹ si i, awọn alawọ-funfun to fẹran ẹlẹyamẹya, ati awọn ti wọn gbagbọ pe ki awọn gba ilẹ awọn pada lọwọ awọn eeyan dudu, nigba to si jẹ Kristẹni ni wọn, inu wọn tun dun pe Trump loun yoo ṣe nnkan si ọrọ awọn Musulumi to wa lọdọ wọn. Nidii eyi lero ṣe pọ lẹyin Trump, bo si tilẹ jẹ pe pupọ ara Amẹrika lo fẹran Hilary Clinton, nitori wọn mọ ọn gẹgẹ bii iyawo Bill Clinton to ti ṣejọba ibẹ ri, ati pe oun ni Barak Obama to n ṣejọba nigba naa ti lẹyin nitori ọmọ ẹgbẹ Democratic kan naa ni wọn jọ n ṣe, sibẹ, Trump ni ọpọ awọn alawọ-funfun Amẹrika dibo fun, ọrọ to n sọ ti jẹ wọn, wọn fara mọ ohun to ni oun fẹẹ ṣe. Apapọ ibo ti Clinton ni ju ti Trump lọ, ṣugbọn nigba to ku ibo awọn aṣoju, ibo to jẹ ti awọn alagbara, Trump fẹyin Hilary janlẹ ni 2016 yii, bẹẹ lo ṣe di aarẹ.

Gbara ti Trump wọle lo ti ṣe ofin rẹ akọkọ, ofin to si ṣe ni pe oun ko fẹ awọn eeyan lati orilẹ-ede awọn Musulumi kan. Lẹẹkan naa, Trump fi ofin de awọn orilẹ-ede meje, pe awọn eeyan wọn ko gbọdọ wọ Amẹrika, nitori ko si ẹni ti yoo fun wọn ni fisa, orilẹ-ede awọn Musulumi ni gbogbo wọn. Ọjọ keje ti wọn ṣebura fun un gẹgẹ bii aarẹ Amẹrika lo gbe ofin naa jade. Awọn orilẹ-ede to fi ofin de yii ni Iran, Iraq, Libya, Somalia, Sudan, Syria ati Yemen. Ọrọ naa di ariwo buruku, koda o di wahala, o si di ohun ti wọn n wọ ijọba rẹ lọ sile-ẹjọ. Ṣugbọn ọkunrin naa ko tori ẹ yi ofin naa pada, bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ to ga ju lọ nibẹ ni ofin ti ko dara ni, ofin buruku ni, ko si ba ofin ilẹ Amẹrika mu. Sibẹ, Trump gba idajọ yii, o si tun wa ọna mi-in lati fi gbe ofin naa jade.

Lati igba naa ni ijaya ti de ba gbogbo aye, ariwo ti wọn si n pa ni pe Amẹrika koriira Musulumi, pe ko fẹran wọn. Trump ko fi bo pe loootọ ni, o ni awọn ki i ṣe Musulumi, Kristẹni lawọn, oun ko si le maa dibọn pe awọn fẹran wọn, o ni awọn ko fẹran wọn rara ni. Ọrọ naa ba gbogbo aye lẹru, nitori nibi yii ni ọpọ awọn orilẹ-ede Musulumi wọnyi ti bẹrẹ si i yẹra fawọn ara Amẹrika, wọn o si fẹẹ ba wọn ṣe. Awọn Musulumi mi-in to ṣe pe Amẹrika ni wọn n gbe tẹlẹ, ti wọn kan sare lọ si orilẹ-ede wọn, ọrọ di iṣoro fun wọn lati wọle pada, nnkan naa si di ohun ti wọn n gbe ijọba Amẹrika lọ sile-ẹjọ lojoojumọ, lori ọrọ fisa, ati awọn Musulumi ti Trump fẹẹ fi tipatipa le jade l’Amẹrika, nigba to jẹ ibẹ ni wọn bi pupọ ninu awọn naa si, wọn ki i ṣe alejo to ṣẹṣẹ wọlu rara. Ọrọ yii ko daamu dabo ba ọpọ eeyan aye, paapaa awọn ti wọn ko ni ile mi-in ju Amẹrika yii lọ.

Nigba naa ni Trump bẹrẹ si i sọ oriṣiiriṣii ọrọ kobakungbe si awọn eeyan dudu, awọn ọrọ buruku to si sọ si Naijiria kọja afẹnusọ. O ni awọn eeyan dudu ti wọn wa ni Amẹrika, bi wọn ṣe n wa si ilu naa ko dara, nitori niṣe ni wọn yoo ni awọn waa kawe, tabi pe awọn waa ki awọn eeyan wọn, ṣugbọn nitori pe ninu ahere oko ni wọn ti jade, nigba ti wọn ba foju kan Amẹrika to jẹ ilu nla, wọn yoo ni awọn ko lọ mọ, wọn yoo waa jokoo, wọn yoo sọ ara wọn di ọmọ oniluu, ko si ni i pẹ ko ni i jinna tawọn naa yoo maa fọwọ lalẹ pe ọmọ oniluu lawọn. O ni ọrọ naa ko dara to, bi awọn alawọ-funfun Amẹrika ko ba si mura daadaa, awọn eeyan naa yoo gba ilu wọn lọwọ wọn. O ni ohun ti oun Trump waa ṣe niyẹn, oun ko ni i jẹ ki iru ẹ ṣẹlẹ laelae. Iwa ẹlẹyamẹya ti ko ṣẹlẹ ri si bẹrẹ si i gbilẹ lojoojumọ si i l’Amẹrika, ija si bẹrẹ si i ṣẹlẹ laarin awọn dudu ati funfun.

Nitori ikoriira ti Trump ni fun awọn dudu yii, o kọ lu wọn ni orilẹ-ede Mexico, nitori o ni awọn ti wọn wa nibẹ naa, adamọdi eeyan dudu ni wọn, awọn eeyan dudu ti wọn sa kuro ni Amẹrika ni wọn gba ibẹ lọ, nitori bẹẹ lo ṣe jẹ kidaa ọdaran lo pọ lọdọ wọn. O ni Mexico yii lawọn amugbo pọ si, bẹẹ lawọn adigunjale, ati awọn ọmọọta. O ni oun ko fẹ wọn niluu wọn mọ. Nitori pe Mexico ati Amẹrika jọ paala, ti ko si ṣoro fawọn ara Mexico yii lati fẹsẹ rin wọ Amẹrika, Trump loun yoo mọ odi nla kan, odi naa yoo si gun to ọtalelọọọdunrun maili, odi naa yoo si ga ti ko ni i sẹni to le gun un, odi yii ni yoo si ṣe aala saarin Mexico ati Amẹrika. Awọn ara Amẹrika binu, wọn ni owo kekere ma kọ ni yoo kọ iru odi bẹẹ yẹn. Ṣugbọn Trump ni ko le, oun yoo gba owo naa lọwọ ijọba ilẹ Mexico, nitori awọn ni wọn n dọgbọn wọ ilu awọn. Ṣugbọn Mexico loun o lowo iru ẹ. Titi ti di bi a ti n wi yii, Trump wa nibi to ti n kọ odi Mexico!

Nigba ti Trump wọle, niṣe ni inu awọn ara Yuroopu dun, wọn ni ẹni ti yoo ba awọn da si ọrọ to n lọ ree. Ọrọ to n lọ nigba naa ni wọn n pe ni Bẹsiiti (Brexit), nigba ti ilẹ United Kingdom ni awọn ko fẹẹ ba awọn orilẹ-ede Yuroopu ṣe ẹgbẹ ti awọn jọ n ṣe mọ, awọn ko fẹẹ si ninu ẹgbẹ European Union mọ, awọn fẹẹ da wa, ki onikaluku maa ṣe tirẹ lọtọọtọ ni. Awọn orilẹ-ede Yuroopu to ku bi Jamani, Spain, Faranse, Italo, ati awọn to ku lawọn ko gba, wọn ni awọn ara UK yoo fi kinni naa ba eto ọrọ aje agbegbe Yuroopu jẹ ni, pe iṣọkan to si ti wa laarin awọn lati bii ọgọrun-un ọdun sẹyin yoo pada di aisiṣọkan, ija ati ede-aiyede. Ni Trump ba lọ sọdọ wọn lọhun-un, ni wọn ba ro pe yoo pari ija fun wọn. Ṣugbọn niṣe lo da kun ija naa, to ti Britain lẹyin pe ki wọn kuro lara Yuroopu, ki wọn jẹ ki awọn jọ maa ṣe, nitori oyinbo kan naa lawọn ni tawọn.

Oriṣiiriṣii awọn iwa irufin mi-in ti ko si olori Amẹrika kan to ṣe iru rẹ ri lo n ti ọwọ Trump jade, ti ija si de laarin oun ati awọn ile igbimọ aṣofin, debii pe oun ati olori ile-igbimọ naa n sọrọ kaṣakaṣa si ara wọn, ijọba rẹ si i le koko. Eyi to waa mu ibinu awọn eeyan dide si i gan-an ni ọrọ arun korona to gba gbogbo ilu kan. Nigba ti arun naa bẹrẹ ni Ṣaina, kia ni awọn akọṣẹmọṣẹ ati awọn ti wọn mọ ohun to le ṣẹlẹ sọ fun ijọba Trump pe ki wọn tete jẹ ki awọn dena arun naa ko ma wọ Amẹrika. Ni Trump ba ni abi ki lo n ṣe awọn eleyii. O ni arun awọn ara Ṣaina ni, ko ni i wọ Amẹrika, nitori ọrijina eeyan funfun lawọn. Afi nigba ti arun naa wọ Amẹrika lojiji, n lo ba bẹrẹ si i pa awọn eeyan nipakupa, nigba toloju yoo si fi ṣẹ ẹ, o ti le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un meji to ba kinni naa lọ.

Nibi ti ọrọ ọkunrin yii de duro niyi bi ibo ti n kanlẹkun, ti awọn aṣiṣe rẹ si n gbilẹ si i. Ki i ṣe ni Amerika nikan n wọn ti koriira rẹ bayii, o fẹrẹ jẹ gbogbo aye ni. Bi ẹ yi sibi, Trump ni o, bi ẹ yi sọhun-un, Trump ni o, wọn ko si sọrọ rẹ naa daadaa. Nigba naa ni awọn ẹgbẹ Democratic jade, wọn ni dandan ni ki awọn gba ijọba Amẹrika lọwọ Trump, bi bẹẹ kọ, bi wọn ba fi aaye gba a lati lo ọdun mẹrin mi-in, o le da ogun agbaye silẹ, tabi ko da Amẹrika ru pata debii pe ko ni i ṣee tun ṣe mọ. Ohun to si tubọ mu ọrọ naa rọrun fun awọn Democratic Party yii ni pe awọn kan ninu awọn ti wọn tẹle Trump ni 2016 lori ọrọ ẹlẹyamẹya ti ri i pe afaimọ ki igbesẹ naa ma da Amẹrika ru, nitori o ti n sọ awọn di ọta ara wọn. Ni wọn ba n pada lẹyin Trump, wọn si n ba Joe Biden ti ẹgbẹ Democratic fa kalẹ lọ.

Gbogbo bi wọn ṣe n ṣe kampeeni ni Trump n leri, to si mu ibo naa kuro ni iru ibo ti wọn maa n di ni Amẹrika, o sọ ọ di ibo ti wọn n di ni awọn ilu ti ko laju rara. Awọn oyinbo naa bẹrẹ si i ni awọn tọọgi ti wọn n ya sita ati awọn ti wọn n ṣewọde pe awọn ko ni i gba ki Joe Biden wọle, wọn ni Trump lawọn fẹ ṣaa. Ọrọ naa ya gbo agbaye lẹnu, nitori wọn ko ri iru ẹ ri. Nigba ti ibo bẹrẹ paapaa, niṣe ni Trump n leri kannaa pe bi Joe Biden ba fi le wọle, oun ko ni i gba rara ni o. Lasiko naa ni awọn ọmọ Naijiria kan gbe iṣe wọn de, ohun to si kan wọn ko yeeyan rara ninu ọrọ ti Amẹrika naa. Ni ilẹ Ibo ni wọn ti bẹrẹ, wọn si bẹrẹ iwọde naa, ti wọn ko ọpọlọpọ awọn eeyan jọ, wọn si n ṣe iwọde kaakiri ilẹ Ibo yii, ti wọn ni Trump lawọn fẹ bii aarẹ Amẹrika lẹẹkan si i.

Nibi yii ni ọrọ akoba ti bẹrẹ, nitori awọn eeyan n sọ nigba naa pe ti wọn ba waa dibo naa, ti Trump ko ba pada wọle, njẹ ẹni to ba wọle yii ko ni i mu Naijiria ati awọn eeyan rẹ gẹgẹ bii ọta, nigba to jẹ orilẹ-ede kan ninu gbogbo aye ti wọn ti ṣatilẹyin fun Donald Trump niyi, ko tun si ibi ti wọn ti ṣe bẹẹ kaakiri aye. Nigba tọrọ naa yoo si ṣẹ bẹẹ, nigba ti esi ibo bẹrẹ si i wọle, awọn eeyan yii naa mọ pe awọn ti ṣe aṣiṣe. Esi ibo to kọkọ wọle fihan pe Trump ti gbẹyẹ lọwọ Biden, n lawọn eeyan ba n jo kiri. Aṣe apa kan ibo naa ni wọn ṣi ka, nigba ti wọn bẹrẹ si i ka apa keji, nnkan daru mọ Trump ati awọn eeyan rẹ lọwọ pata, o si han pe ibo bii miliọnu marun-un o din diẹ ni Biden fi na ọkunrin naa ni anafọju. Sibẹ naa, Trump ko ti i fẹẹ gba pe wọn na oun, ni awọn oniroyin agbaye ba tu esi idibo naa jade, wọn si kede pe Joe Biden lo wọle.

Bayii ni Amẹrika ni aarẹ tuntun.

Ẹru to n ba awọn onimọ eto oṣelu aye bayii ni pe njẹ awọn ọmọ Naijiria ko ti fi iwọde buruku yii ko ba orilẹ-ede yii bayii? Kin ni yoo ṣẹlẹ laarin ijọba Joe Biden ati awọn ọmọ Naijiria, paapaa awọn ti ko mọwọ mẹsẹ ninu ohun ti awọn wọnyi ṣe. Ko si ẹni to ti i mọ ibi ti ọrọ naa yoo fi si, gbogbo aye lo ṣaa n dunnu bayii pe Trump ti lọ, ọkunrin kan ṣoṣo to ko gbogbo aye lọkan soke!

Leave a Reply