Aarẹ bii Buhari ni Ọlọrun yoo tun fun wa ni 2023- Gomina Ebonyi

“Mo maa n sọ pe ọwọ Ọlọrun ni agbara wa, Ọlọrun yoo tun fun wa ni Aarẹ mi-in to ni ọkan rere bii Buhari, ki nnkan le daa lorilẹ-ede yii”

Wọnyi lọrọ Gomina ipinlẹ Ebonyi, Ọgbẹni Dave Umahi, lọjọ Aje ọsẹ yii, nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin to ṣepade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari tan l’Abuja.

Gomina Umahi gboriyin fun Aarẹ Muhammadu Buhari lori awọn iṣẹ kan to ṣe ni Guusu Ila-Oorun Naijiria, paapaa biriiji ti wọn n pe ni Second Niger Bridge, eyi ti gomina yii ṣalaye pe o ti n gba oju ọwọ bayii. Bakan naa lo ni Buhari kare lori ọna reluwee to n ṣe fawọn ẹya Ibo.

Lori idi ti Gomina Ebonyi ṣe n ṣe awọn alaye yii nipa Buhari, ọkunrin naa sọ pe ẹni ba ṣeun, ka lo ṣeun ni. O loun waa ri Aarẹ l’Abuja koun le dupẹ lọwọ rẹ lori awọn iṣẹ to ṣẹ yii ni.

O ni biriiji yẹn da bii ala ni, awọn ko mọ pe yoo wa si imuṣẹ, bẹẹ naa si ni ọna reluwee to pese naa yoo mu ilọsiwaju ba ọrọ-aje awọn olugbe Ebonyi.

O fi kun un pe laye igba toun n lọ sileewe, ọkọ reluwee loun maa n wọ lati Ebonyi lọ si Maiduguri, nibi tawọn ẹgbọn oun wa. O ni Buhari lo tun fẹẹ jẹ kiru ẹ ṣee ṣe pada bayii pẹlu ọkọ oju irin, oun atawọn olugbe Ebonyi si dupẹ lọwọ rẹ gidi.

O ni boun ṣe tun foju kan Buhari loun ran an leti pe ko ma gbagbe bo ṣe loun yoo ṣe awọn akanṣe iṣẹ si awọn olu-ilu ilẹ Ibo, gomina yii ni ṣugbọn wọn ko ranti fi Abakaliki ti i ṣe olu-ilu Ebonyi si i, wọn si yọ Awka naa kuro, iyẹn olu-ilu Anambra, ko si yẹ koun dakẹ bẹẹ lai ran Aarẹ leti.

Umahi tun sọrọ lori iṣẹ ọgbin, o ni bi ko ba si ti Buhari  to fun awọn agbẹ ni ajilẹ, to tun ṣe awọn eto mi-in fun wọn, nnkan ko ba le gan-an fun orilẹ-ede yii labala ounjẹ.

Bakan naa lo ni awọn iṣẹ kan wa ti Buhari ti fọwọ si, to si ti yawo rẹ sọtọ nipinlẹ Ebonyi, bẹẹ lo si ṣe ifilọlẹ awọn kan nigba to ṣabẹwo sibẹ. Gomina Umahi ni gbogbo awọn nnkan to ṣẹku yii loun tori ẹ waa ri Aarẹ l’Abuja, koun si dupẹ lọwọ rẹ fawọn to ti ṣe.

O ni ṣugbọn to ba jẹ ti ọkan rere ni, Buhari lọkan rere fun Naijiria, Ọlọrun yoo si tun fun wa ni Aarẹ bii rẹ lẹẹkan si i.

Leave a Reply