Monisọla Saka
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni Aare orilẹ-ede yii, Muhammadu Buhari, ṣadeede gbera lai kede tabi pero rẹ tẹlẹ lati lọọ wo awọn eeyan mẹtalelogun ti wọn ṣẹṣẹ tu silẹ, ti wọn si tun jẹ ọwọ to kẹyin lara awọn tawọn ikọ Boko Haram ko sigbekun lati ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2022 yii, nile iwosan Defence Academy, ti wọn gbe wọn lọ fun itọju to peye niluu Kaduna.
Oluranlọwọ ileeṣẹ Aarẹ lori eto iroyin, Garba Sheu, lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade kan to fi lede l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, to pe akọle ẹ ni, ‘Buhari lọọ yọju sawọn ti wọn bọ nigbekun Boko Haram, o fẹmi imoore han sawọn ileeṣẹ ologun’.
Gẹgẹ bi Sheu ṣe sọ, Aarẹ Buhari ṣabẹwo si ọsibitu ti wọn ko awọn mẹtalelogun to ṣẹku sọdọ awọn agbebọn to da ọkọ oju irin to n lọ lati Abuja si Kaduna toun tawọn ero inu ẹ duro lati inu oṣu Kẹta, ọdun yii. Lẹyin ti Buhari yẹ awọn mọkandinlaaadọrin (69) ti wọn ṣẹṣẹ kẹkọọ jade nile-iwe ẹkọṣẹ ologun ilẹ wa, NDA, to wa ni Afaka, nipinlẹ Kaduna, si tan lo yọju sawọn eeyan ọhun nile iwosan ti wọn ti n gba itọju.
O tẹsiwaju pe ko too di pe o wọ baaluu ileeṣẹ ologun oju ofurufu NAF 001, pada si ilu Abuja lati papakọ ofurufu ipinlẹ Kaduna ni Buhari ti ya bara lọ si ile iwosan lati lọọ ki awọn ti wọn ṣẹṣẹ gba itusilẹ ku oriire, nibẹ naa lo ti dupẹ lọwọ awọn ileeṣẹ ologun fun iwa akin ti wọn hu lati ri awọn eeyan naa gba silẹ laaye ati lalaafia, o ni orilẹ-ede yii ko ni i gbagbe oore nla ti wọn ṣe naa titi lae”.
Ki a ranti pe, laago mẹrin irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, lawọn ikọ agbesunmọmi Boko Haram tu awọn to gbẹyin ni igbekun wọn silẹ lati bii oṣu mẹfa sẹyin ti wọn ti ko awọn ero naa.
Lara awọn ti wọn wa nileewosan lasiko abẹwo Aarẹ naa ni, Adari igbimọ ti ọga awọn ologun gbe kalẹ, Major General Usman Abdulkadir, to ṣe akitiyan bi wọn ṣe tu awọn eeyan ọhun silẹ, Major General Adamu Jalingo, Brigadier General Abubakar Saad, Dokita Murtala Rufai, Ibrahim Abdullahi, Ahmed Magaji, Ọjọgbọn Yusuf Usman to jẹ akọwe igbimọ ọhun ati Ọga awọn Ologun, General Lucky Irabor.