Ni ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii ni Aarẹ Muhammadu Buhari fun oludije sipo gomina nipinlẹ Edo, Osagie Ize-Iyamu, ni asia ẹgbẹ oṣelu APC lati dije dupo gomina ipinlẹ Edo ninu eto idibo ti yoo waye ninu oṣu kẹsan-an ọdun yii.
Inu ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ize-Iyamu wa telẹ ko too darapọ mọ ẹgbẹ APC, nibi ti wọn ti fa a kalẹ lati dije dupo gomina lorukọ ẹgbẹ wọn.
Oun ni yoo koju Godwin Obaseki to n ṣe gomina Ẹdo lọwọ. Ẹgbẹ oṣelu APC lọkunrin yii wa tẹlẹ. Ede aiyede to ṣẹlẹ laarin oun ati baba isalẹ rẹ nidii oṣelu, Adams Osihomhole, lo sọ ọ dero ẹgbẹ oṣelu PDP, nibi ti wọn ti fa a kalẹ lati dije dupo gomina lorukọ ẹgbẹ wọn.
Alaga afun-un-ṣọ ẹgbẹ APC, to tun jẹ gomina ipinlẹ Yobe, Malla Buni naa wa nibẹ lati gba a wọle.