Aarẹ Buhari ko ṣatilẹyin kankan fun ẹgbẹ-Miyetti Allah
- Adewale Adeoye
Ẹgbẹ awọn Fulani daran-daran, ‘Coalition Of Cattle Breeders Association’ lorileede yii, Miyetti Allah, ti sọ pe ki i ṣohun to daa rara bi Aarẹ Muhammadu Buhari ko ṣe gbe igbesẹ kankan lati fopin si bawọn ọdaran kan ṣe n pa awọn Fulani laarin ilu atawọn ẹran wọn ninu igbo lọpọ igba, eyi ti wọn sọ pe yoo jẹ iṣoro nla bi Buhari ba fi le kuro lori aleefa bayii.
Wọn ni ki i ṣohun to daa rara bi Aarẹ Buhari ko ṣe da sọrọ ija to maa n waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ Fulani daran–daran yii atawọn agbẹ gbogbo, tija ọhun si maa n mu ọpọ ẹmi lọ.
Wọn ni owo to to bii biliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta Naira nijọba Aarẹ Buhari na lori ọrọ ọgbin lorileede yii lakooko iṣakoso rẹ, ti ko si nawo kankan sẹgbẹ awọn titi to fi pari iṣakoso ọdun mẹjọ rẹ bayii.
Ninu ọrọ aarẹ ẹgbẹ awọn daran-daran, MACBAN, Baba Othmanọkan nigba to n ba awọn oniroyin kan sọrọ nipa awọn ohun toju awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ri lakooko iṣakoso Buhari lo ti bẹnu atẹ lu iṣakoso ijọba ọkunrin naa gẹgẹ bii eyi ti ko fawọn lọrọ sọ rara laarin ilu, ti ko si tun ṣe awọn ohun gbogbo tawọn n beere fun rara.
O ni, ‘ Latigba ti wọn ti n jẹ aarẹ lorileede yii, a ko jiya to eyi ta a jẹ nigba isakoso ijọba Aarẹ Buhari yii ri rara. Ojoojumọ ni wọn fi n pa awọn ọmọ ẹgbẹ wa atawọn ẹran wọn ninu igbo, tijọba Buhari ko si rohun gidi kankan ṣe si i rara. Ijọba rẹ ko tu wa lara rara, bẹẹ lo kọ lati wa ojutuu sija gbogbo igba to maa n waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ wa atawọn agbẹ to n gbin nnkan.