Aarẹ Buhari mu Tinubu yika inu Aso Rock, l’Abuja

Adewale Adeoye

Leyin ti won kirun Jimọ tan lọjọ Eti, Furaidee, ọjọ Kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ni Aarẹ orileede yii, Muhammadu Buhari, mu aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan sipo lorileede wa, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, yika gbogbo inu ile agbara ti wọn n pe ni Aso Rock, niluu Abuja, to si ṣalaye awọn nnkan kọọkan fun un nipa bi yoo ti ṣe maa gbẹsẹ ni gbara to ba ti gbajọba orileede yii lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii.

ALAROYE gbọ pe gbara ti wọn pari irun Jumat, eyi tawọn mejeeji jọ ọ ki papọ ninu mọṣalaaṣi nla kan to wa ninu ile ijọba naa ni Aarẹ Buhari ṣafihan naa fun Tinubu, to si n sọ awon ibi gbogbo to ṣe pataki daadaa fun un ninu ọgba ile naa gẹgẹ bii ohun to gbọdọ mọ ko too di aarẹ orileede yii.

Lara awọn ibi to ṣe pataki daadaa ti Aarẹ Buhari ṣafihan rẹ fun Tinubu ni aaye gbalasa kan bayii tawọn igbimọ ti yoo maa ba Tinubu ṣiṣẹ papọ yoo ti maa ṣẹpade pẹlu rẹ nigba gbogbo, atawọn ibomi-in to ṣe koko lati mọ. Bi wọn ṣe jade lati inu ibi ti Aarẹ Buhari ti n ṣafihan fun Tinubu lawọn oniroyin kan ti n duro de Aarẹ Buhari lati beere awọn ọrọ kọọkan lọwọ rẹ, eyi ti wọn ka kun ọrọ igbeyin pẹlu awọn oniroyin naa gẹgẹ bii aarẹ ilẹ yii.

Bẹẹ o ba gbagbe, iyawo aarẹ ilẹ wa, Aisha Buhari, lo kọko mu iyawo aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu, yika inu agbala ile ijọba ti wọn n pe ni Aso Rock, to si ṣafihan awọn ibi ti aarẹ tuntun pẹlu iyawo rẹ yoo maa gbe ni gbara ti wọn ba ti gbe ọpa aṣẹ le wọn lọwọ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Aisha Buhari ṣafihan pataki ọhun fun iyawo Tinubu.

Ninu fidio naa ni Aisha Buhari ti mu Olurẹmi wọle, to si ṣalaye fun un pe awọn ti ko gbogbo ẹru awọn kuro ninu ileejọba, oun ati ọkọ oun ti wa nibi ti wọn n pe ni ile onigilaasi, iyẹn Glass House. O ni ile yii ni awọn ti wọn ba fẹẹ kuro nileejọba yoo maa duro si.

O waa gba iyawo aarẹ tuntun to fẹẹ wọle naa nimọran pe ki wọn ri i bii aṣa pe ile gilaasi yii ni aarẹ to ba n lọ yoo maa wa titi ti ọjọ ti wọn yoo kuro nileejọba yoo fi pe.

Nigba to n sọrọ lori abẹwo naa,  Olurẹmi Tinubu ni abẹwo naa je eyi to mu inu oun dun.

Leave a Reply