Aarẹ orileede yii, Muhammadu Buhari, ti fi orileede Naijiria silẹ, o ti lọ si London.
Lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni ọkan ninu awọn baalu ijọba gbe e lati papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe, to wa niluu Abuja.
Buhari n lọ si irinajo yii pẹlu bi awọn ẹgbẹ oniṣegun ilẹ wa ṣe ni awọn maa bẹrẹ iyanṣẹlodi ni ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹrin, ọdun yii.
Lasiko irinajo yii, Aarẹ Buhari yoo fẹsẹ kan de ọsibitu lati ṣayẹwo ara rẹ gẹgẹ bi Oludamọran rẹ lori eto iroyin, Fẹmi Adeṣina, ṣe sọ. Inu ọsẹ keji, ninu oṣu kẹrin, ọdun yii, nireti wa pe yoo pada si Naijiria.