Aarẹ Buhari yoo ba gbogbo ọmọ Naijiria sọrọ laago meje alẹ yii

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe oun yoo ba gbogbo ọmọ Naijiria sọrọ laago meje alẹ oni.

Oludamọran Aarẹ lori eto iroyin, Femi Adesina, lo sọrọ naa ninu atẹjade to fi sita ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

O rọ gbogbo ileeṣẹ redio ati telifiṣan lati dara pọ mọ telifiṣan ilẹ wa, NTA, fun ọrọ ti Aarẹ Buhari fẹẹ ba gbogbo ọmọ ilẹ yii sọ.

Leave a Reply