Aderounmu Kazeem
Ni kete ti wọn ti sọ fun un wi pe Ọlọrun ti ko o yọ lọwọ arun buruku to kọlu yii lo ti gba ori ẹrọ abẹyẹfo ẹ lọ, nibẹ lo si ti ba gbogbo awọn eeyan e sọrọ, to si fi wọn lọkan balẹ wi pe ara oun ti le daadaa, ati pe bi ara oun ṣe ya lasiko yii, o fẹẹ maa ri bẹẹ lati bii ogun ọdun sẹyin.
Lasiko ti ikede ipolongo ibo sipo aarẹ orile-ede Amẹrika n lọ lọwọ ni arun ọhun kọlu u, eyi to mu un fagile pupọ ninu awọn eto to ti la silẹ. Ṣugbọn ni bayii to ti bọ lọwọ arun Koro, Donald Trump yoo le tẹ siwaju pẹlu eto ipolongo rẹ bayii.
Ninu ọrọ ẹ to sọ lo ti ni, “E ma ṣe bẹru arun koro o, orilẹ-ede wa ti ni idagbasoke to le koju ẹ daadaa. Ijọba Donald Trump ti ṣiṣẹ takuntakun lati pese oogun to le koju arun ọhun, ati pe ọgbọn gidi n be fun wa pẹlu. Fun idi eyi, ẹ ko gbọdọ jẹ ki arun kankan ko ipaya ba a yin, ijọba Trump kaju ẹ daadaa”