Aarẹ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun gbe igbimọ ti yoo ri si awuyewuye idibo gomina Ekiti kalẹ

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Arẹ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, Adajọ Monica Bolna’an Dongban-Mensem, ti ṣagbekalẹ awọn igbimọ ti yoo ri si awuyewuye lẹyin idibo gomina ipinlẹ Ekiti.

Awọn ọmọ igbimọ naa ni yoo ri si iwe ati ipenija to waye lẹyin idibo naa.

Ninu iwe kan ti wọn fi ṣowọ s’awọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọsẹ yii niluu Ado-Ekiti, ti akọwe awọn igbimọ naa, Ogbeni Umar Abubakar, fọwọ si, sọ pe Onidaajọ Bolna’an Dongban-Mensem, lo ṣe agbekalẹ igbimọ naa pẹlu ibamu iwe ofin kejidinlọgbọn ti ọdun 1999, pẹlu ayipada iwe ofin idibo ti ọdun 2022.

Gẹgẹ bi iwe naa ṣe sọ “lgbesẹ yii waye pẹlu aṣẹ ti ofin orile-ede Naijiria ti ọdun 1999 fun aarẹ Ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lati ṣe agbekalẹ igbimọ ti yoo ri si ẹjọ ti yoo waye lẹyin idibo.

“Nidii eyi, Agbefọba agba nipinlẹ Ekiti, Onidaajọ Adelẹyẹ Adeyẹyẹ, ti pese aaye silẹ lati lo gbangan Ile-ẹjọ giga ti ipinlẹ Ekiti to wa ni agbegbe Fajuyi gẹgẹ bii ibujoko awọn igbimọ naa.

Iwe naa rọ gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ekiti ti wọn ba ni ẹsun kan tabi omiiran ki wọn kan si awọn ọmọ igbimọ naa ni gbangan ile-ẹjọ giga naa lati fi iwe ẹsun wọn ṣọwọ si wọn.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: