Aarẹ Tinubu fi biliọnu lọna aaadọrun-un (90b) sanwo iranwọ fawọn to n lọ si Mecca lọdun yii

Adewale Adeoye

Owo tiye rẹ to aadọrun bilionu Naira (N90B) ni olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, fi ṣeranlọwọ fawọn eeyan orileede yii ti wọn n lọ siluu Mecca, lorileede Saudi Arabia, lati lọọ ṣiṣẹ Hajj tọdun yii.

Igbakeji Aarẹ, Alhaji Shettima, lo sọrọ ọhun di mimọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, osu Karun-un, ọdun 2024 yii, niluu Kebbi, lasiko to n ba awọn araalu naa ti wọn n lọ siluu Mecca sọrọ ni papakọ ofurufu ‘Sir Ahmadu Bello International Airport, to wa niluu Birnin Kebbi, nipinlẹ Kebbi.

Ọdọọdun lawọn ẹlẹsin Musulumu jake-jado agbaye maa n lọ siluu Mecca lorileede Saudi Arabia lati lọọ ṣe opo karun-un ninu ẹsin Islam, ti ko si yọ awọn ọmọ orileede Nigeria sile.

Owo tabua ni ajọ to n ṣeto irin-ajo lọ siluu Mecca, iyẹn ajọ ‘National Hajj Commission of Nigeria’ (NAHCON) kede pe awọn ọmọ ilẹ wa to fẹẹ rinrin-ajo naa maa san lọdun yii, nitori bi owo Naira wa ṣe n fojoojumọ ja silẹ lọja paṣi-paarọ agbaaye. Eyi, atawọn ohun mi-in to n ṣẹlẹ lo mu ki owo tawọn to n lọ siluu Mecca lọdun yii lọ soke ju bo ṣe yẹ lọ, to si n mu kawọn araalu kan maa pariwo pe nnkan ko fara rọ mọ laarin ilu, paapaa ju lọ fawọn to fẹẹ lọọ sin Ọlọrun Oba Allah.

Miliọnu mẹrin aabọ Naira (N4.5M)  ni wọn kọkọ kede pe awọn to n lọ siluu Mecca lati Oke-Ọya maa san, ṣugbọn ko pẹ ti wọn tun ṣafikun owo naa, to si di miliọnu marun-un o din ẹgbẹrun lọna irinwo Naira (N4.6M)

Nigba tawọn to n lọ lati ilẹ kaaaro-oo-jiire maa san miliọnu marun-un o din ẹgbẹrun lọna igba Naira (N4.8M).

Lasiko ti Igbakeji Aarẹ n sọrọ lo gboṣuba nla fun ijọba Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu fun bo ṣe n ṣiṣẹ takuntakun labẹnu to si gbe owo nla kalẹ lati fi ṣeranlọwọ fawọn ti wọn n lọ siluu Mecca fun ti Hajj ọdun yii.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘Nitori pe olori orileede yii mọ ipa pataki ti ẹsin n ko nigbesi aye awọn eeyan, ijọba orileede yii ti yan awọn kọọkan ti wọn lorukọ daadaa laarin ilu, ti wọn si tun kunju oṣuwọn daadaa lati bojuto bi eto Hajj tọdun yii ṣe maa lọ deede lai si wahala kankan lasiko ti wọn ba wa lọhun-un, ati bi won ba n pada bọ sile. Ijọba orileede yii ti ṣeranlọwọ owo nla fawọn to n lọ si Mecca lọdun yii, ki ọpọ le lanfaani lati rinirin-ajo naa gẹgẹ bi wọn ṣe fẹ.

Owo tiye rẹ to aadọrun bilionu Naira (N90B) ni Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, fi ṣeranlọwọ fawọn ti wọn n lọ si Mecca tọdun yii.

Awọn ọmọ orileede yii kan ti n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba Bọla Tinubu lati ṣe iranlọwọ owo to to aadọrun-un biliọnu Naira (90B) fun awọn ti wọn fẹẹ rinrin-ajo lọ si ilẹ mimọ lọdun yii. Wọn ni bii igba ti ijọba ko mọ eyi to kan ni pẹlu gbogbo bi nnkan ṣe ri niluu, ti awọn eeyan ko rowo jẹun. Wọn ni ki i ṣe dandan ki ijọba gbe iru igbesẹ yii.

Nigba to n sọrọ lori igbesẹ naa lori ayelujara, Isaac Fayoṣe, to jẹ aburo gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọ Fayoṣe, ti bẹnu atẹ lu igbesẹ naa. O ni, ‘’Ijọba sanwo iranwọ biliọnu lọna aadọrin fun awọn ti wọn fẹẹ lọ si Mecca, bii igba teeyan ko mọ eyi to kan ni. Bi wọn ba pin owo naa ni miliọnu meji meji tabi miliọnu marun-un marun-un fun awọn ọdọ ti wọn n fẹsẹ gba igboro kiri lai riṣẹ, o daju pe awọn bii ẹgbẹrun meji si mẹta ni yoo jẹ anfaani yii bi wọn ba fun wọn ni ẹgbẹrun marun-un marun-un. Ẹni to ba ti jẹun kanu lo n lọ si Hajj tabi Jerusalem.

‘‘Awọn oṣiṣẹ ti n bẹ ijọba lati ọjọ yii lati fi kun owo-oṣu wọn lati bii ọdun kan, ẹ n sọ pe ẹgbẹrun mejilelogoji lẹ fẹẹ fun wọn, ti gbogbo wa si mọ pe ko le sanwo epo ọkọ wọn lasan. Bi ẹ ko ba fowo kun owo awọn oṣiṣe, o tumọ si pe ẹ n faaye gba iwa ibajẹ laarin awọn oṣiṣẹ ni. Biliọnu lọna aadọrun ti pọ ju lati na lori ọrọ Hajj, bii igba ti eeyan ko mọ ohun to fẹẹ fowo ṣe ni.

Bakan naa ni ẹlomi-in sọ pe o jẹ nnkan to ba ni ninu jẹ pe wọn le fowo kun owo Hajj atii Jerusalem, ṣugbọn wọn ko le pese owo iranwọ lori epo bẹntiroolu fun awọn mẹkunnu.

 

Leave a Reply