Aarẹ Trump ni ki Biden ma ti i dunnu o, ipade dile-ẹjọ

Faith Adebọla, Eko

Lai ka ti bawọn eeyan ṣe n rọjo ikini ku oriire fun Ọgbẹni Joe Biden ti wọn ṣẹṣẹ kede rẹ bii Aarẹ tuntun fun orileede Amẹrika si, Aarẹ orileede naa, Donald Trump, ti ni ọrọ ibo yii ko ti i pari rara o, bẹẹ loun ko si reti ijo ọpẹ kan lẹsẹ Biden, tori lọsẹ ta a fẹẹ mu yii loun yoo gba kootu lọ lati pẹjọ lori ibo ti wọn di ọhun.

Ọsan ọjọ Abamẹta, Satide, ni Trump sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sọrọ lori abajade ibo to fẹyin rẹ janlẹ ọhun, Trump ni ibo ko ti i pari rara.

O sọ siwaju pe “Gbogbo wa la mọ idi ti Joe Biden fi n sare kede ara rẹ bii ẹni to jawe olubori, ati idi ti awọn oniroyin rẹ fi n ṣagbatẹru fun un, tori wọn fẹẹ daṣọ bo otitọ mọlẹ ni, gbogbo aṣiri to wa nibẹ lo si ti han si wa. Ọrọ ibo yii ko ti i pari rara.”

Trump ni jibiti ati wayo ṣẹlẹ ninu ibo yii, oun ko si ni i gba ki ọrọ naa lọ wọọrọwọ bẹẹ, ile-ẹjọ gbọdọ ba awọn da si i.

Ọsan ọjọ Abamẹta, ni wọn kede Joe Biden to dije ipo aarẹ Amẹrika lati ẹgbẹ Democrats gẹgẹ bii olubori, nigba ti Aarẹ Trump to dijẹ labẹ asia Republican fidi rẹmi

Leave a Reply