Aayun lo dija Ogidan ati ọga ẹ silẹ, diẹ lo ku ko ge ‘kinni’ abẹ ẹ ja bọ l’Ogere

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Beeyan ko ba lọkan akin, ko ni i le wo bi nnkan ọmọkunrin Oluwo Shakiru ṣe ri lasiko yii, ẹpọn ọkunrin naa ti re kuro nibẹ ni ka wi. Bẹẹ, Ogidan Yusuf, ẹni ogoji ọdun ti wọn jọ n ṣiṣẹ lo fọwọ lasan ba aye ẹpọn naa jẹ, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kọkanla, nibi kan ti wọn n pe ni Ogere Junction.

Olori ogun ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ogun, CP David Akinrẹmi, lo fiṣẹlẹ yii to ALAROYE leti nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun.

O ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹsan-aabọ aarọ ọjọ Aje, Mọnde, niṣẹlẹ yii waye. O ni Ogidan Yussuf to n gbe l’Opopona Wuraọla, l’Epẹ, n ṣiṣẹ agegi ninu igbo lọdọ Shakiru ni, iyẹn lo n sanwo iṣẹ fun un.

Ohun to fa ija lọjọ Mọnde naa ti Ogidan fi sọ ọga ẹ dẹni to dubulẹ sile iwosan bayii ko ju ọrọ aayun (Saw), ti wọn fi n gegi lọ.

Shakiru mu aayun naa fun Ogidan lati lo o loko, nigba to si to asiko to yẹ ko da a pada, Ogidan ko da aayun naa pada, eyi lọga rẹ beere lọwọ ẹ to fi dohun to sọ ọ di alaabọ ara.

Kọmandanti Akinrẹmi sọ pe niṣe ni Ogidan sọ fun ọga ẹ pe ọlọdẹ to n ṣọ inu igbo toun ti lọọ gegi lo gba aayun naa lọwọ oun lọsẹ meloo seyin, o si ti gbẹsẹ le e, oun ko le ri i gba pada mọ.

Esi ti Ogidan fọ yii ko tẹ Shakiru lọrun, o ni dandan ko lọọ ba oun wa irinṣẹ naa wa.

Ọrọ yii ni wọn n fa lọwọ to fi di pe o kan iyawo Shakiru naa, iyawo da si i pe ki lo de ti Ogidan ko da aayun ọkọ oun pada, to n fa wahala bii eyi. Iyẹn lo bi Ogidan ninu, lo ba ni ki lo kan iyawo Shakiru nibẹ to fi n da si i, n lo ba fun iyawo naa ni igbati to le.

Ohun to waa fa gidigbo ree laarin awọn ọkunrin meji yii, lo di pe ọga ati ọmọṣẹ n lu ara wọn. Nibi tija naa ti n lọ lọwọ ni Ogidan ti bẹrẹ mọlẹ, lo tawọ si ẹpọn Shakiru, o si n fa a bii ko ja.

Ko fi kinni naa silẹ bọrọ, afigba to bu apa kan rẹ danu, ti ẹjẹ waa n ṣe bala nibi nnkan ọmọkunrin Oluwo Shakiru, ti ọkunrin naa si n jẹrora to lagbara.

Wọn sare gbe e lọ sileewosan jẹnẹra Ọlabisi Ọnabanjọ Yunifasiti, fun itọju. Itọju ọhun bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ, ṣugbọn bi oju apa yoo ṣe jọ oju ara nipa ọlọmọkunrin leeyan ko ti i le sọ.

Awọn Amọtẹkun Ila-Oorun Ijẹbu ti wọn fọrọ lọ lo sare mu Ogidan to huwa ọdaran, ko si ba wọn jiyan, o ni loootọ loun sọ ‘kinni’ ọga oun di korofo mọ ọn labẹ.

Awọn Amọtẹkun naa fa a fọlọpaa lẹyin ti wọn pari iṣẹ tiwọn, ọlọpaa ni yoo ṣeto bi yoo ṣe de kootu, ti yoo lọọ ṣalaye ohun to de to fi baye ọkunrin bii tiẹ jẹ bẹẹ.

Ṣugbọn ko sẹni to ri ohun ti Ogidan ṣe yii ti wọn ko maa sọ pe emi Eṣu n gbenu rẹ, wọn ni bo ṣe fọwọ lasan ṣeka to to bayii, tọwọ iru ẹ ba tẹ ibọn tabi ada, ko ni i wo o lẹẹmeji ti yoo fi bẹ eeyan lori feu.

Leave a Reply