Abayọmi  to n ta oogun oloro fawọn akẹkọọ FUNAAB bọ sọwọ NDLEA l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọkunrin kan, Abayọmi Popoọla, to n gbe niluu Eko, ṣugbọn to maa n ta oogun oloro fawọn akẹkọọ kan nileewe imọ ọgbin, FUNAAB, l’Abẹokuta, ti bọ sọwọ ajọ NDLEA  to n ri si oogun oloro bayii.

Ilu Abẹokuta ni wọn ti mu oun ati ọlọkada to maa n ba a gbe e lọ fawọn onibaara, ẹni ti wọn pe orukọ tiẹ ni Ogah.

ALAROYE gbọ pe o pẹ ti ajọ NDLEA ti n wa Abayọmi, nitori wọn ti n gbọ nipa rẹ pe iṣẹ buruku to n ṣe niyẹn.

Ọkan ninu awọn iṣẹ agbofinro nilẹ wa lọkunrin naa n ṣe lọdọ ijọba Eko, ṣugbọn eyi to mu ni koko ju ni tita oogun oloro yii.

Nigba ti wọn mu oun ati Ọgah lagbegbe Camp, l’Abẹokuta, l’Ọjọruu to kọja, igo Codeine mẹtadinlogun, igbo onikilo mejilelogun, Tramadol 230 onigiraamu mejidinlọgọrun-un, oogun kan ti wọn n pe ni  Flunitrazepam mọkanlelọgọta, oogun kan naa ti wọn n pe ni Molly, ati ọkan ti wọn ni ibalopọ lo wa fun, toun naa din diẹ laaadọta ni awọn NDLEA ba lọwọ awọn mejeeji.

Wọn tun ba oogun oloro mi-in ti wọn pe orukọ ẹ ni Colorado lọwọ Ogah, a si gbọ pe awọn akẹkọọ FUNAAB to n ra kinni naa lọwọ ẹ ti mọ ọn bii owo.

Koda, nigba tawọn NDLEA mu awọn mejeeji, niṣe lawọn kan ninu awọn akẹkọọ naa di wọn lọna, ti wọn ni awọn ẹṣọ ajọ naa ko ni i kọja, afi ti wọn ba fi Ogah ati ọga rẹ to n ta oogun oloro  fawọn silẹ.

Awọn alajọṣiṣẹpọ Abayọmi ati Ogah ni wọn ni wọn ko awọn akẹkọọ naa jọ lati di ọna kawọn ajọ to mu wọn ma baa kọja, ṣugbọn lẹyin wakati diẹ ti wọn ti n fa a, wọn gbe awọn afurasi meji naa lọ sagọọ ajọ yii.

Ọga ẹka iroyin fun ajọ NDLEA, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, ṣalaye pe iwadii fidi ẹ mulẹ pe ṣọọbu iyawo Abayọmi ni wọn maa n ja awọn oogun oloro yii si, wọn si tun maa n ta a nibẹ naa fawọn onibaara wọn.

Bi Abayọmi Popoọla ba fi le jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an lori oogun oloro yii, iṣẹ ijọba to n ṣe naa yoo bọ lọwọ rẹ gẹgẹ bi wọn ṣe wi, oun ati ikeji rẹ yii yoo si jiya to wa fun nini oogun oloro nikaawọ ati tita a fawọn eeyan mi-in.

Leave a Reply