Abba Kyari gba kootu lọ, o ni kile-ẹjọ foun ni beeli nitori ailera oun

Faith Adebọla

 Gbajugbaja ọga ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ nni, Abba Kyari, ti wọn fẹsun kan pe o n ṣe okoowo egboogi oloro ati iwa jibiti, ti wọn si tori ẹ mu un sahaamọ ajọ NDLEA to n gbogun ti iru awọn ẹṣẹ yii, ti pe ijọba apapọ lẹjọ, o si ti beere pe kile-ẹjọ foun ni beeli tori ailera oun.

Agbẹjọro rẹ, C. O. Ikena, sọ ninu iwe ipẹjọ ti nọmba rẹ jẹ FHC/ANJ/CS/182/22, pe bi ajọ NDLEA ṣe mu onibaara oun sahaamọ tẹ ẹtọ ọmọniyan ati ominira rẹ loju, tori onibaara oun ko jẹbi ẹsun ti wọn tori ẹ mu un, o si rọ ile-ẹjọ naa pe ki wọn paṣẹ lati tu Abba Kyari silẹ, ko maa ti ile waa jẹjọ, ko si le ri itọju iṣegun gba nitori ailera rẹ.

Adajọ ile-ẹjọ naa, Inyang Ekwo, beere lọwọ agbejọro ọhun pe ibo ni onibaara rẹ wa, o si fesi pe akata ajọ NDLEA ni, ladajọ ba ni ki wọn kọkọ lọọ jẹ ki NDLEA mọ nipa ẹjọ yii, ati ibeere fun beeli to mu wa. O loun ko le paṣẹ beeli fun Abba Kyari nigba ti olufisun rẹ ko ti i gbọ nipa ẹjọ naa.

Lọọya naa ṣalaye fun adajọ pe ara Abba Kyari ko ya gidigidi, o si nilo itọju iṣegun, ṣugbọn adajọ ko gba alaye rẹ wọle, o si da a nu bii omi iṣanwọ.
O sun igbẹjọ lori ẹsun titẹ ẹtọ ọmọniyan Kyari loju si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹrin, ọdun yii, o si paṣẹ pe ki ajọ NDLEA fesi si ẹsun ifiyajẹni ati titẹ ẹtọ Kyari mọlẹ ṣaaju ki ọjọ igbẹjọ to n bọ too pe.

Leave a Reply