Abba Kyari loun ko jẹbi ẹsun siṣe agbodegba oogun oloro

Jọkẹ Amọri

Ẹsun mẹjọ ọtọọtọ ni ile-ẹjọ kan to jokoo niluu Abuja, niwaju Onidaajọ Emeka Nwite fi kan igbakeji kọmiṣanna nilẹ wa ti wọn ti jawee gbele-ẹ fun bayii, Abba Kyari, lori gbigbe oogun oloro, ṣugbọn ọkunrin naa ni oun ko jẹbi.

Lara ẹsun naa ni igbimọ-pọ lati lufin, gbigbegi dina iwadii, gbigbe oogun oloro ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ile-ẹjọ ka a si wọn leti bayii pe ‘‘Iwọ Kyari, igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa, ACP Sunday J. Ubuah, ASP Bawa James, Insipẹkitọ Simon Agirigba ati Insipẹkitọ John Nuhu ti gbogbo yin jẹ ọkunrin, ni ọjọ kọkandinlogun si ikẹẹẹdọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ti ẹ jẹ oṣiṣẹ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si awọn iwa ọdaran to ba lagbara niluu Abuja, to wa ni agbegbe ti ile-ẹjọ yii le gbọ ẹjọ le lori gbimọ-pọ, ṣe agbodegba kokeeni ti iwọn rẹ din diẹ ni kilo mejidinlogun lai gba aṣẹ. Nipa bayii, ẹ ṣẹ si si ofin to de ileeṣẹ to n gbogun ti lilo ati tita oogun oloro (NDLEA), to si ni ijiya labẹ ofin.

Bakan naa ni adajọ tun ka a siwaju pe, ‘‘Pe iwọ Abba Kyari pẹlu ACP Sunday J. Ubuah, ASP Bawa James, Insipẹkitọ Simon Agirigba ati Insipẹkitọ John Nuhu to ti sa lọ bayii fọwọ kan kokeeni kilo mẹẹẹdọgbọn ati diẹ (21.35), ti ẹ gba lọwọ Chibunna Patrick Umeibe ati Emeka Alphonsos Ezenwanne, lọna ti ko bofin mu.

‘‘Ẹ yọ kilo to le diẹ ni mẹtadinlogun nibẹ, ẹ si fi nnkan mi-in paarọ rẹ. Pẹlu ohun ti ẹ ṣe yii, ẹ ti ṣẹ sofin iwa ọdaran to ni ijiya ninu ofin to de ajọ to n gbogun ti gbigbe oogun oloro ati lilo.

Bakan naa ni adajọ tun fẹsun kan wọn pe wọn fẹ ki ileeṣẹ NDLEA ṣe agbodegba pẹlu wọn bi wọn ṣe fun wọn ni riba ẹgbẹrun mejilelọgọta owo dọla ($61, 400)  ki wọn maa baa ṣayẹwo si ayederu kokeeni to fi rọpo eyi to jẹ ojulowo ti wọn gba lọwọ awọn to gbe e.

Pẹlu ohun ti wọn ṣe yii, adajọ ni wọn ṣẹ sofin to de iwa ọdaran labẹ ileeṣẹ to n gbogun ti oogun oloro. Nigba ti wọn ka awọn ẹsun yii si ọga ọlọpaa naa leti, o ni oun ko jẹbi ọkankan ninu wọn. Bẹẹ lawọn ọmọọṣẹ rẹ naa ni awọn ko jẹbi.

Ṣugbọn Umeibe ati Ezenwanne ti wọn gba oogun oloro naa lọwọ wọn ni awọn jẹbi gbigbe oogun oloro ni tawọn.

Leave a Reply