Abdullahi ti dero ẹwọn o, ile onile lo lọọ fọ n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ẹwọn oṣu mejila pẹlu iṣẹ aṣekara ladajọ ileejọ Majisireeti kan to fi ilu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, ṣe ibujokoo ju Abdulsalam Abdullahi, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o lọọ ji Plasma TV tu lagbegbe Ìtẹ̀síwájúrere, lẹyin Harmony Estate. Ajọ ṣifu difẹnsi lo wọ ọdaran yii lọ siwaju ile-ẹjọ pe Abdullahi wọ ile onile, to si lọọ ji Plasma TV meji nibẹ ko too di pe ọwọ palaba rẹ ṣegi.

Alukoro ajọ ṣifu difẹnsi ni Kwara, Michael Sọla Ayọọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni Abdullahi lọọ ji Plasma TV meji tu lagbegbe Harmony Estate, niluu Ilọrin, nigba ti awọn onile gba a mu ni wọn gbe e wa si ọfiisi awọn. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe nigba to tu akọkọ tan lo gbe e kalẹ, to si bẹrẹ si i tu ikeji, ṣugbọn nigba to kẹẹfin pe awọn onile n bọ lo sa gun ori aja lọ, ko too di pe ọwọ tẹ ẹ.

Ayọọla tẹsiwaju pe lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii ni awọn taari ọdaran naa lọ siwaju ile-ẹjọ Majisireeti kan to wa lagbegbe Sáńgò, niluu Ilọrin, nibi ti adajọ ti ni ko lọọ fi aṣọ penpe roko ọba fun oṣu mejila gbako, eyi to ni yoo jẹ ẹkọ fawọn to ba tun fẹẹ hu irufẹ iwa buruku bẹẹ.

 

Leave a Reply