Abdulmalik yoo ṣẹwọn o, miliọnu rẹpẹtẹ lo wọ jade lakaunti ileeṣẹ kan

Adewale Adeoye
Adajọ ile-ejọ kan niluu Ikeja, nipinlẹ Eko, Onidaajọ Abikẹ Fadipẹ, ti sọ Ọgbẹni Abdulmalik Abdullateef, ti ajọ to n gbogun tiwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku nilẹ wa ‘Economic And Financial Crimes Commision’ (EFCC), mu wa siwaju rẹ sẹwọn ọdun kan pẹlu iṣẹ aṣekara.
Ọjọbọ, Tosidee, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ni EFCC tun foju Abdulmalik bale-ẹjọ lori ẹsun pe o lu ileeṣẹ ‘Fincra Technology,’ to wa niluu Eko, ni jibiti miliọnu mẹwaa Naira.
Ṣaaju akooko naa, iyẹn lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2023 yii, ni wọn ti kọkọ foju rẹ bale-ẹjọ, to si rawọ ẹbẹ si adajọ kootu ọhun pe ki wọn ṣiju aanu wo oun, loootọ loun jẹbi gbogbo awọn ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan oun yii.
Ninu ọrọ olupẹjọ to n ṣoju ajọ EFCC, Ọgbẹni S.O Deji, lo ti ṣalaye ni kootu pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ naa to nimọ daadaa nipa ẹrọ kọmputa, Ọgbẹni Damilare Adeọṣun, lati waa sọhun to mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan Abdulmalik.
Adeọṣun fidi rẹ mulẹ pe lẹyin ti ajọ naa gba ipe pajawiri latọdọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ti Abdullmalik lu ni jibiti, ‘Fincra Technology’, lawọn bẹrẹ iṣẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an, ti ẹri to daju si wa fawọn pe o din diẹ ni miliọnu lọna ọọdunrun Naira lọdaran naa wọ kuro ninu akanti ileeṣẹ ọhun lọna aitọ. Gbara to si ṣiṣẹ ibi naa tan lo sa lọ si ipinlẹ Kaduna. Ibẹ ni wọn ti lọọ fọwọ ofin mu un wa siluu Eko, nibi to ti jẹwọ pe loootọ lohun huwa buruku naa.
Lara awọn ohun ta a ba lọwọ rẹ ni foonu igbalode Iphone ‘12 Pro’ meji ati Iphone 11 Pro ẹyọ kan. Gbogbo rẹ pata lo si ti wa lọdọ ajọ EFCC bayii.
Ọmọkunrin naa waa bẹ adajọ pe ko ṣiju aanu wo oun, nitori oun ti ronupiwada kuro ninu iṣẹ ibi naa. Abdulmalik ni oun ti ri i pe ki i ṣohun to daa rara keeyan maa lu jibiti laarin ilu, ati pe oun paapaa ti di ẹni ọtun bayii latigba toun ti loore-ọfẹ lati wọle sileewe Fasiti Kaduna.
Bakan naa ni agbẹjọro rẹ, M.A Zulobi, bẹ adajọ pe ko ṣiju aanu wo onibaara oun.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Abikẹ Fadipẹ sọ ọ sẹwọn ọdun kan pẹlu iṣẹ aṣekara, ninu ọkan lara ọgba ẹwọn to wa niluu Eko, tabi ko lọọ gba aarin ọja fun igba wakati.
Bakan naa lo ni ki ajọ EFCC gbẹsẹ le gbogbo awọn ẹru ati owo ti wọn gba lọwọ rẹ pata.

Leave a Reply