Abdulrahman ti ha o, kẹkẹ Marwa lo lọọ ji gbe ni mọṣalaaṣi

Adeoye Adewale

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Jimeta, lẹgbẹẹ ọja igbalode kan to wa niluu Yola, nipinlẹ Adamawa, ti sọ pe ọdọ awọn ni Ọgbẹni Abdulraman Ishaq, ẹni ọdun mejilelogun, ti wọn fẹsun kan pe o ji Kẹkẹ Marwa kan. Wọn ni gbogbo ọrọ tawọn n beere lọwọ rẹ pata lo n da awọn lohun daadaa, to si n ran awọn lọwọ ninu iwadii awọn bayii. Wọn ni gbara tawọn ba ti pari iṣẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an tan lawọn ti maa taari rẹ lọ siwaju adajọ ile-ẹjọ, ko le lọọ kawọ pọyin rojọ niwaju adajọ.

ALAROYE gbọ pe ẹsun iwa ole jija ni wọn fi kan Abdulraman, ẹni ti wọn sọ pe agbegbe Geriyo, nijọba ibilẹ Yola North lo n gbe, to si lọ sagbegbe Jimeta, ni mọṣalaaṣi Jimọh nla kan, to si lọọ ji Kẹkẹ Marwa kan nibẹ.

Ohun ta a gbọ ni pe ṣe ni Abdulraman wo raaraara lakooko tawọn olujọsin n kirun lọwọ ni Mọṣalaṣi nla naa, nigba ti ko rẹnikankan nitosi lo ba ji Kẹkẹ Marwa kan ti wọn paaki sẹgbẹẹ geeti ninu ọgba naa, to si lọọ bo o mọ ibi kan. Ṣugbọn awọn kọọkan ti wọn ti mọ pe bi wọn ti ṣe maa n ji Kẹkẹ Marwa lagbegbe naa niyẹn ni wọn ba bẹrẹ si i wa Kẹkẹ Marwa naa, ti wọn si ba a lọwọ Abdulraman, nibi to ti n gbiyanju lati ji i gbe sa lọ.

Loju-ẹsẹ naa ni wọn ti fa a le ọlọpaa agbegbe  naa lọwọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Suleiman Ngurojẹ, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawon oniroyin lọjọ Abamẹta, Satidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, sọ pe loootọ ni Abdulraman gbero lati ji Kẹkẹ Marwa naa ko too di pe ọwọ tẹ ẹ.

Nguroje ni, ‘‘Iwadii ta a ṣe nipa Abdulraman fi han pe ṣe lo fẹẹ ji Kẹkẹ Marwa naa gbe nibi ti ẹni to ni i gbe e si. Ẹnu ọna abawọle kẹrin ti wọn n pe ni ‘geeti 4’, ni ẹni to ni Kẹkẹ Marwa naa paaki Kẹkẹ Marwa rẹ si, to si wọnu Mọṣalaṣi lọ lati lọọ kirun, ṣugbọn ti Abdulraman ji i gbe kuro nibi tẹni to ni i gbe e si, bi wọn ṣe ti n wa Kẹkẹ Marwa naa ni wọn ka a mọ Abdulraman lọwọ lakooko to fẹẹ ji i gbe sa lọ. Awọn araalu naa ko fiya to pọ jẹ Abdulraman rara, wọn kan fọwọ ba a diẹ ni, ko too di pe wọn fa a le ọlọpaa lọwọ.

Alukoro ni Abdulraman ti wa lọdọ awọn bayii, to si n ran awọn lọwọ ninu iwadii awọn lati mọ idi pataki to fi jẹ pe Kẹkẹ Marwa nikan ni awọn ọdaran agbegbe naa maa n saaba ji gbe bayii.

Nguroje ni, ‘Aipẹ yii ni Ọgbẹni Suleiman Auwal, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan lọọ ji Kẹkẹ Marwa ninu ọgba mọṣalaṣi ọhun, to si n gun kaakiri ko too di pe ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ lakooko to fi n gbero.

‘A maa too foju Abdulraman bale-ẹjọ lori ohun to ṣe yii, ko le jiya ẹṣẹ rẹ lẹkun-un-rẹrẹ.

Leave a Reply