Abẹẹ ri Kayọde, ọmọ bibi inu ẹ lo n ba sun n’Ifọ

Gbenga Amos, Ogun

Baba ẹni aadọta ọdun kan, Olukayọde Joshua, tọwọ awọn ẹṣọ alaabo So-Safe ipinlẹ Ogun tẹ laduugbo Ọlambẹ, n’Ifọ, ti jẹwọ o, o ni loootọ loun n ba ọmọ bibi inu oun ti ko ju ọdun mẹrinla laṣepọ, ṣugbọn ko ti i ju ẹẹkan pere lọ.

Ọga agba ẹṣọ alaabo Social Orientation and Safety Corps, So-Safe, Kọmadaati Sọji Ganzallo, lo fiṣẹlẹ yii to ALAROYE leti lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Kẹwaa yii, ninu atẹjade kan.

Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn aladuugbo ti awo ọrọ naa lu si lọwọ ni wọn tẹ ileeṣẹ So-Safe laago lati fi to wọn leti. Eyi lo si ṣamọna bi wọn ṣe lọọ fi pampẹ ofin gbe afurasi ọdaran naa nile rẹ to wa ni Akinbọ Phase 2, nidojukọ ile Ọla Fatia, to wa laduugbo Ọlambẹ, Ifọ, ipinlẹ Ogun, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, ọṣu Kẹwaa, yii kan naa.

Wọn lọpẹlọpẹ awọn ẹṣọ So-Safe, ẹka ti Oke-Aro/Ọlambẹ, ti Ọgbẹni Akeem Ọlaiya lewaju fun, bi wọn ṣe tete debi iṣẹlẹ ọhun ni ko jẹ kawọn ọdọ tinu n bi lu afurasi ọdaran naa pa, tori wọn n din dundu iya fun un lọwọ ni wọn debẹ, ti wọn si gba a lọwọ wọn, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe e.

Ni ọfiisi awọn ẹṣọ naa, wọn ni niṣe baba ọmọdebinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri yii bu sẹkun, o jẹwọ pe loootọ ni ibalopọ waye laarin oun atọmọ bibi inu oun, ṣugbọn ki i ṣe lemọlemọ tawọn aladuugbo n sọ yẹn o, o ni akọkọ oun re e, ẹẹkan pere naa loun ṣi huwa aidaa ọhun.

Wọn lọkunrin naa ni oun o lo oogun abẹnugọngọ lati fipa b’ọmọ oun sun o, bẹẹ loun funra oun o loogun amarale kankan, ṣugbọn bi gbogbo ẹ ṣe waye ṣi n ru oun loju, oun ko mọ bo ṣe ṣẹlẹ, oun kan ri i pe o ti ṣẹlẹ naa ni.

Ganzallo ni wọn mu ole lẹẹkan, o loun o wa ri, bi awijare rẹ ba tọna, bi ko ba si tọna, awọn ti fa afurasi ọdaran yii le ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lọwọ, ki wọn le tubọ ṣewadii to lọọrin, ki wọn si gbe igbesẹ to bofin mu lori Kayọde, oni’kinni’ ko-mọ-ẹbi yii.

Leave a Reply