Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Panpẹ ofin ti mu ọkunrin yii, Ọlaoluwa Jimọh, ẹni ọdun marundinlaaadọta (45) to fun ọmọ bibi inu ẹ ti ko ju ọdun mọkàndínlógún(19) lọ loyun l’Ode-Rẹmọ, nipinlẹ Ogun.
Ọmọbinrin ẹ to fun loyun naa lo lọọ fẹjọ rẹ sun ni teṣan Ode-Rẹmọ, nibẹ lo ti ṣalaye pe iya oun ko fẹ baba oun mọ lọdun to ti pẹ, ọdọ iya naa loun si wa latigba naa ko too di ọdun meji sẹyin ti baba oun ni koun maa bọ l’Ode-Rẹmọ kawọn jọ maa gbe, boun ṣe dero ọdọ rẹ niyẹn.
Ọmọ naa sọ pe afi bo ṣe di asiko kan ninu oṣu kẹfa, ọdun 2021 yii, ti baba oun wọle tọ oun ni yara, to si fipa ko ibasun to le foun.
O ni latigba naa lo ti sọ abẹ oun di ounjẹ ti ko le ma jẹ, to jẹ niṣe lo ṣaa n ba oun sun gidigidi, to si n kilọ pe oun ko gbọdọ sọ ohun to n ṣẹlẹ naa feeyan laye, o ni lọjọ toun ba sọ pẹnrẹn loun raye mọ.
Eyi lọmọ paapaa ko ṣe sọrọ naa fẹnikan gẹgẹ bo ṣe wi, afigba ti ere buruku ti wọn jọ n ṣe naa di oyun, ti ọmọ Ọlaoluwa loyun fun un.
Oyun tọmọ naa ni bayii ti ko mọ ohun ti yoo ṣe si i lo jẹ ko kuku lọọ ṣalaye ara ẹ fawọn ọlọpaa lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan-an yii, ti CSP Faṣọgbọn Ọlayẹmi, DPO teṣan naa, fi ran awọn ọlọpaa lati lọọ mu baba yii wa.
Nigba to n ṣalaye ara ẹ fawọn agbofinro, Ọlaoluwa Jimọh jẹwọ pe loootọ loun ti n ba ọmọ oun sun lati oṣu kẹfa, ọdun yii. O ni ẹjọ
oun naa kọ, Eṣu lo ti oun debẹ, iṣẹ Eṣu ni.
Wọn ti gbe e lọ sẹka to n wadii iwa ọdaran bii eyi, gẹgẹ bii aṣẹ kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun.