Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti tẹ gende-kunrin kan, Wasiu Afọlabi, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24). Irọ bantabanta lo gbe kalẹ pe wọn ji oun gbe, to si n beere owo itusilẹ lọwọ awọnobi rẹ.
Gẹgẹ bi Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Victor Ọlaiya, ṣe sọ, ọkunrin kan, Lekan Afọlabi, to n gbe niluu Amọ́yọ̀, lo mẹsun wa si agọ ọlọpaa pe awọn ajinigbe ti ji aburo oun kan ti orukọ rẹ n jẹ Wasiu Afọlabi, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ti wọn si n beere miliọnu mẹta Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ, ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ ati idunaadura, wọn gba pe awọn yoo gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (500,000), ti wọn aa si kọkọ sanwo asan-an lẹ ẹgbẹrun lọna igba Naira (200,000), eyi to mu ki ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ iwadii.
Wọn pada mu Wasiu Afọlabi nigba ti wọn ti mọ pe o ji ara rẹ gbe pamọ ni, to si fẹẹ fi gbowo lọwọ awọn obi rẹ ni.
Ọlaiya, ni ọwọ tun tẹ Moshood Sulaiman, to jẹ oniṣowo POS, to n gbe ni agbegbe Ọ̀yun, ti wọn fi akanti rẹ gbowo.
Wasiu jẹwọ pe loootọ ni oun ji ara oun gbe pamọ lati le gbowo lọwọ awọn ọrẹ ati mọlẹbi oun.
Ọlaiya ni iwadii ti bẹrẹ, ati pe ni kete to ba ti pari lawọn yoo wọ awọn mejeeji lọ siwaju adajọ.