Abẹrẹ ajẹsara arun Korona ti de s’Ekoo, Ọṣun

 Faith Adebọla, Eko, Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Abẹrẹ ajẹsara lati dena arun Koronafairọọsi to n ja ranyin kari aye ti de siluu Eko, ijọba apapọ lo fi i ranṣẹ latilu Abuja.

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, lo kede pe awọn ti gba abẹrẹ ajẹsara ti wọn porukọ ẹ ni AstraZeneca COVID-19 naa laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, awọn si ti lọọ tọju ẹ pamọ sibi ti eera kan o ti ni i rin in, kawọn too bẹrẹ si i fawọn eeyan.

Sanwo-Olu sọrọ yii nibi apero itagbangba kan to waye niluu Ikẹja, lati sami ayẹyẹ ayajọ awọn obinrin lagbaaye (International Women’s Day), tọdun yii.

Gomina ni bo tilẹ jẹ pe awọn maa ṣeto lati jẹ kawọn eeyan janfaani abẹrẹ ajẹsara naa, eyi o tumọ si pe kawọn eeyan ma pa ilana ati ofin ijọba lori idena arun Korona mọ, o ni wọn ṣi ni lati maa lo ibomu, fifọwọ loorekoore ati yiyẹra fun ikorajọpọ ero.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ keji, oṣu kẹta yii, ni miliọnu mẹrin abẹrẹ ajẹsara naa de latilu oyinbo, tijọba apapọ si tẹwọ gba a niluu Abuja, lẹyin naa ni wọn lawọn maa ṣeto ati pin in kari awọn ipinlẹ gbogbo nilẹ wa.

Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Ọṣun, labẹ idari Gomina Adegboyega Oyetọla ti kede pe abẹrẹ ajẹsara Korona ọhun ti balẹ si ipinlẹ naa latọdọ ijọba apapọ, l’Abuja.

Kọmiṣanna feto iroyin ati ilana antẹle, Funkẹ Ẹgbẹmọde, ni ni nnkan bii aago meje alẹ kọja ogun iṣẹju lọjọ Iṣẹgun, Wẹsidee, ọsẹ yii ni wọn ri abẹrẹ naa gba.

Papakọ ofurufu to wa niluu Akurẹ lawọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọṣun ti lọọ gba awọn abẹrẹ naa.

Ẹgbẹmọde ṣalaye pe ijọba ti mura silẹ lati fun awọn araalu labẹrẹ naa nipasẹ awọn akọṣẹmọṣẹ oniṣegun oyinbo ti wọn ti fun nidanilẹkọọ to peye lori abẹrẹ naa kaakiri wọọdu ojilelọọọdunrun-un o din mẹjọ to wa l’Ọṣun.

O fi ọkan awọn araalu balẹ lori abẹrẹ naa, o ṣalaye pe ajọ NAFDAC ti ṣayẹwo finnifinni le e lori, wọn si ri i pe ko si ewu kankan nipa rẹ.

Bakan naa lo ni ki wọn ma titori abẹrẹ naa pa gbogbo ilana to wa nilẹ fun idena itankalẹ arun Korona ti, ki wọn maa ṣe ohun to tọ nibi gbogbo ti wọn ba wa.

 

Leave a Reply