Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to kọja yii, ni akẹkọọ kan nile ẹkọ olukọni agba Kinsey, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, Ahmed Yusuf, ṣeku pa alabaagbe rẹ, Farouk Ojo Ahmed, nitori abọ ounjẹ.
Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe agbegbe Fate, niluu Ilọrin, ni awọn mejeeji gbale si ti wọn n gbe, ṣugbọn sadeede ni aawọ bẹ silẹ laarin wọn latari pe wọn o gbọ ara wọn ye mọ lori bi wọn ṣe n dana pọ, jẹun pọ, eyi lo mu ki Yusuf sọ pe oun yoo ko awọn abọ ti wọn lo tẹlẹ tori pe wọn o le dana pọ mọ. Lasiko ti Farouk dari de lati mọṣalaaṣi ni Yusuf lọọ ṣakọlu si i, to si gun un lọbẹ pa.
Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ti a fi orukọ bo laṣiri to ba ALAROYE, sọrọ sọ pe awọn mejeeji ni aawọ bẹ silẹ laarin wọn latari pe Farouk ti wọn gun pa ni o maa saaba fi owo silẹ ti wọn ba fẹ dana, ti Yusuf yoo si maa sọ pe oun ko lowo, eyi lo ni o da aawọ naa silẹ, wọn gbinyanju lati pari aawọ ọhun, ṣugbọn pabo lo ja si, to si pada jẹ pe Yusuf sẹku pa ẹnikeji rẹ ti wọn jọ n gbele.