Abi iru ki waa leleyii, nitori ti ko paasi idanwo, Adegoke pokunso l’Ọffa

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọmọ ileewe girama Ọffa, Adegoke Adeyẹmi, ẹni ọdun mẹtadinlogun, ti ku bayii, wọn ni tori pe ko paasi idanwo lo ṣe lọọ pokunso.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fi sita l’Ọjọruu, Wẹsidee, lo ti sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ẹka tilu Ọffa, nipinlẹ Kwara, lo gba ipe pajawiri kan ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, pe wọn ri oku ọdọkunrin kan to n rọ dẹdẹ lagbegbe Ileetura Ariya Garden, niluu Ọffa.

Nigba ti awọn ọlọpaa de ibi iṣẹlẹ naa ni wọn ri i pe Adegoke Adeyẹmi ni ọmọkunrin ọhun, ẹni ti wọn sọ pe ileewe girama ilu Ọffa, lo n lọ. O ṣe idanwo SS1, lati bọ si SS2, ṣugbọn o fidi rẹmi, wọn si ni yoo tun SS1 ka, eyi lo ṣokunfa to fi lọọ pokunso, to si seku pa ara rẹ lojiji.

Ọkasanmi ni wọn ti gbe oku ọmọ naa lọ si ileewosan Jẹnẹra tilu Ọffa, fun ayẹwo ti iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.

Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, CP Tuesday Assayomo psc (+) rọ awọn obi ki wọn maa sọ irinsi awọn ọmọ, ki wọn si maa fifẹ han si wọn nigba gbogbo.

Leave a Reply