Abi iru ki waa leleyii, wọn tun ri oku obinrin kan leti odo n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Lowurọ kutu, ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni wọn tun ri oku obinrin  kan leti odo Amule, Abata Karumọ, eyi to wa ni agbegbe Seriki Kaun, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.

Alaga ẹgbẹ idagbasoke agbegbe naa, Mallam Abdulrazaq Abubakar, to ba ALAROYE, sọrọ sọ pe bi awọn ṣe ji ni owurọ kutu ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, lawọn ri oku obinrin ọhun ni eti odo, ti ko si sẹni to mọ ẹni to gbe oku naa sibẹ.

O tẹsiwaju pe ki oku naa ma baa di wahala laduugbo ni wọn ṣe lọọ ke si awọn ọlọpaa, nigba ti awọn ọlọpaa de ni wọn sọ pe ki wọn ya fọto rẹ ti wọn si ni awọn nilo lati gba aṣẹ ki wọn too gbe e lọ.

Arabinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Iya Ibo sọ pe inu ile ni oun wa ni Garaaji Sao, ti wọn fi sọ pe iṣẹlẹ abami naa waye, ti oun si lọ sibi iṣẹlẹ naa lati fidi otitọ mulẹ. Ni bayii, awọn ọlọpaa ti gbe oku arabinrin ọhun lọ, ti wọn si ni awọn yoo ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply