Abidemi ko janduku lọ sileewe nitori ọmọ ẹ ti olukọ ba wi, wọn fẹẹ ṣa tiṣa naa pa l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

To ba pẹ ju kawọn alaṣẹ ileewe Baptist Girls College, Idiaba,  l’Abẹokuta, too pe ọlọpaa ni, boya tiṣa kan ko ba ti dero ọrun ninu awọn oṣiṣẹ ibẹ lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejila, oṣu kẹwaa yii. Ọkunrin kan, Abidemi Oluwaṣeun, lo ko janduku meji lẹyin pẹlu ada lọwọ, ti wọn lawọn yoo ṣa tiṣa kan to lu ọmọ Abidemi nileewe naa pa.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, to fi iṣẹlẹ naa ṣọwọ ṣalaye pe ọmọ ọdun mẹẹẹdogun ni ọmọ Abidemi, obinrin si ni.

O ni ọmọ naa pẹlu awọn akẹkọọ kan ni wọn jọ n fi tiṣa ṣe yẹyẹ nigba ti iyẹn n kọ wọn lọwọ, bẹẹ ni wọn n fariwo daamu kilaasi, ti wọn ko jẹ kawọn akẹkọọ yooku gbọ ohun ti olukọ n sọ.

Eyi lo lo bi tiṣa naa ninu to fi lu ọmọ Abidemi atawọn ti wọn jọ n da kilaasi laamu naa, ki wọn le sinmi palapala. Afi bi ọmọ Abidemi ṣe gba ile lọ, to si sọ fun baba rẹ pe tiṣa lu oun.

Ohun ti baba naa gbọ ree to fi kan si awọn ọkunrin meji yii; Fayeṣele Ọlabanji (ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn) ati Alebioṣu Quawiyu (ẹni ọdun mẹrinlelogun), ni awọn mẹtẹẹta ba gbe mọto ayọkẹlẹ kan ti ko ni nọmba lara, o di ileewe ti wọn ti lu ọmọ Abidemi. Ada tuntun ṣaṣa kan ni wọn mu dani pẹlu ileri pe awọn yoo ṣa tiṣa to lu ọmọbinrin naa pa.

Bi wọn ṣe de ileewe Baptist Girls College naa ni wọn sọ ijangbọn kalẹ, wọn n wa tiṣa to ba ọmọ wọn wi, kawọn naa le da sẹria fun un. Ṣugbọn awọn alaṣẹ ileewe naa sare pe awọn ọlọpaa Kemta, CSP Ọpẹbiyi Sunday, to wa nibẹ si tete ran awọn ikọ rẹ lọ sileewe yii, awọn ni wọn da awọn to fẹẹ ṣa tiṣa ladaa naa lẹkun, ti wọn si fọwọ ofin mu wọn pẹlu mọto ti ko ni nọmba ti wọn gbe wa.

Nigba to n ṣalaye ara ẹ, Abidemi ti tiṣa lu ọmọ ẹ sọ pe oun loun gba awọn meji yooku naa pe ki wọn waa ba oun kọ tiṣa yii lọgbọn, ohun to jẹ kawọn jọ wa niyẹn pẹlu ada tawọn fẹẹ fi ṣoro fun un.

Ni bayii, Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki wọn wadii awọn ọkunrin mẹta yii daadaa, ki wọn si taari wọn si kootu laipẹ rara.

Leave a Reply