Abikẹ Dabiri binu si ileeṣẹ tẹlifiṣan Arise

Monisọla Saka

Olori ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria to wa lẹyin odi, ‘Nigerians in Diaspora Commission’, NIDCOM, Abikẹ Dabiri-Erewa, ti fi ibinu ṣekilọ fun ọga ileeṣẹ tẹlifiṣan Arise, lati tọwọ awọn ọmọọṣẹ rẹ bọṣọ, ko si tun kọ wọn ni bi wọn ṣe n sọrọ lori afẹfẹ.

Dabiri fi ẹdun ọkan rẹ han lori ọrọ kan tawọn sọrọsọrọ nileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ọhun sọ lasiko ti wọn n sọrọ lori nnkan ti ọkunrin ọmọ orilẹ-ede Naijiria to fi oke okun ṣebugbe, to si tun ni ikanni ayelujara YouTube, iyẹn Emdee Tiamiyu ṣe.

Tiamiyu yii ni wọn lo ṣe ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC, eyi ti ayọrisi rẹ pada ṣokunfa bi wọn ṣe dena awọn ọmọ Naijiria atawọn ààrè mi-in ti wọn n kawe lorilẹ-ede UK, lati mu mọlẹbi wọn wa.

Ninu fọnran kan ti wọn gbe sori ẹrọ ayelujara ni ọkunrin kan ti wọn n pe ni Arewa Daddy ati Ayọ Mairo-Ese, ti wọn jẹ olootu eto lori tẹlifiṣan Arise TV, lori eto kan ti wọn maa n ṣe laraarọ ti bu ẹnu atẹ lu Aarẹ Muhammadu Buhari lori bo ṣe sọ awọn ọmọ Naijiria di ẹni yẹpẹrẹ niwaju ijọba Ilẹ UK, nigba to pe awọn ọmọ Naijiria ni ọlẹ, ati pe Abikẹ funra ẹ ti pe awọn ọmọ Naijiria ni ọmọ ẹgbẹ okunkun ati ogbologboo elegboogi oloro ri.

O ni, “Mi o mọ’di tawọn ọmọ Naijiria ṣe maa n ba ara wọn je loju awọn eeyan agbanla aye. Ẹ jẹ ka wo nnkan to waye lọdun 2016, Aarẹ wa pe awọn ọdọ ilẹ Naijiria ni ọlẹ. Ati pe ilẹ UK ko gbọdọ gba wọn laaye lati sa si abẹ wọn nitori ọdaran ni pupọ ninu wọn.

Adari ajọ NIDCOM naa, Dabiri, pe awọn ọmọ Naijiria ni ọmọ ẹgbẹ okunkun ati elegboogi oloro. O tumọ si pe nnkan ti Emdee Tiamiyu sọ ko yatọ si nnkan tawọn aṣaaju wa naa n sọ”.

Ibinu ọrọ ti obinrin yii sọ ni Abikẹ ba lọ si ori opo abẹyẹfo Twitter rẹ lati wẹ ara rẹ mọ lori ọrọ ti wọn sọ, to si tun ke si ẹni to jẹ ọga fun wọn nileeṣẹ naa lati jawe akiwọwọ fawọn ọmọ abẹ ẹ.

Abikẹ gbe ọrọ ẹ lati ori gbogbo ilakaka to ti ṣe lati de ipo to wa yii, o ni, “Mo ṣiṣẹ karakara lati debi ti mo wa lonii yii ni, ta a ba waa ri obinrin kan ti ọjọ ori tabi nnkan to ti ko jọ laye ko le duro lẹgbẹẹ tiẹ, to waa ro pe ọna lati ja ọ walẹ, ko sọ ẹ di ero ẹyin ni lati maa tutukutu lẹnu, a jẹ pe wọn yoo ko onitiwọn naa. Ki ọga wọn, Nduka Obaigbena, jẹ kilọ fawọn ọmọbinrin ti wọn n sọrọ lori tẹlifiṣan Arise TV, ko ki wọn nilọ, ki wọn ma kọja aaye wọn”.

Awuyewuye yii waye latari ifọrọwerọ Tiamiyu to gbajumọ fun bo ṣe maa n gba awọn ọmọ Naijiria to fẹẹ waa kawe lorilẹ-ede United Kingdom, nimọran lori opo ayelujara YouTube ẹ, nibi ti Tiamiyu ti lọọ fọgba ayanga lori BBC, to ni awọn ọmọ Naijiria ti wọn fẹẹ kawe ni UK ko ṣe e nitori nnkan mi-in ju ọna lati mori bọ, ki wọn si sa kuro nilẹ Naijiria lọ.

O ni ọrọ alekun iwe kika kọ lo ba awọn ọmọ Naijiria ti wọn n wa eto ẹkọ niluu wọn, bi ko ṣe bi wọn yoo ṣe bẹrẹ igbe aye ọtun nibẹ.

“Ọna iwe kika yẹn da bii gbigba adura fawọn ọmọ Naijiria ni. Nitori anfaani nla lo jẹ lati le ko ọpọlọpọ eeyan, atawọn eeyan ti wọn o fi bẹẹ jẹ nnkan kan wọle. A ti bẹrẹ si i ri i bayii pe ọpọlọpọ eeyan lo gọ sẹyin pe awọn fẹ waa kawe ni. Irọ nla ni ọrọ iwe kika yẹn, ki i ṣe pe wọn nilo iwe ti wọn n parọ pe awọn fẹẹ ka, wọn fẹẹ japa ni”.

Tiamiyu la ọrọ mọlẹ debi pe, nigba ti oyinbo yẹn tun beere itumọ japa, o ṣalaye fun un pe aṣa tawọn ọmọ Naijiria ti wọn n sa kuro niluu n da ni.

Aṣiri ọrọ yii to tu lo ṣokunfa ofin tuntun ti orilẹ-ede naa ṣe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, pe yatọ sawọn to ba fẹẹ gboye imọ ijinlẹ ọmọwe (PhD), ko saaye fun kiko mọlẹbi wọle wa mọ fun ẹnikẹni to ba fẹẹ kawe mọ.

Bo tilẹ jẹ pe Tiamiyu n le furukọkọ lori ayelujara pe ijọba UK n bẹ lẹyin oun pẹlu bawọn ọmọ Naijiria kan ṣe n halẹ mọ oun labẹ aṣọ. Lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, lo tun gba ori ẹrọ ayelujara lọ lati tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria, atawọn orilẹ-ede mi-in to ti fi ọrọ ẹnu ẹ ko ba.

Leave a Reply