Abimbọla at’ọrẹkunrin ẹ lọọ sa pamọ I’Ekiti, ni wọn ba ranṣẹ sile pe wọn ji awọn gbe

 Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Fun dida ọgbọn alumọkọrọyi lati gba owo lọwọ awọn obi wọn, awọn ololufẹ meji, Suluka  Abimbọla, ọmọ ọdun mẹrindinlogun, ati ololufẹ rẹ Oluwaṣeun Ọlajide, ẹni ọdun mẹtadinlogun, ti wa ni atimọle ọlọpaa nipinlẹ Ekiti bayii.

Agbẹnusọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣalaye pe ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni obinrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan ti orukọ rẹ n jẹ Bọlaji Fẹmi to n gbe ni agbegbe Bawa, niluu Ado-Ekiti, wa si agọ ọlọpaa to wa ni opopona to lọ si ilu iyin-Ekiti, to si sọ fawọn agbofinro pe aburo oun ti orukọ rẹ n jẹ Suluka Abimbọla jade nile laaarọ ọjọ naa pe oun n lọ sileewe, ṣugbọn awọn ko ri i ko pada wale titi di asiko ti oun waa fi ọrọ naa lọ awọn ọlọpaa.

Alukoro awọn ọlọpaa yii fi kun un pe ileewe Christ School, Ado-Ekiti, ni ọmọbinrin yii n lọ, wọn si reti rẹ titi, ṣugbọn ko pada wa sile.

Wọn pe ẹrọ ilewọ rẹ, ẹnikan ti wọn ko mọ si gbe e, o sọ fun wọn pe awọn ajinigbe ti ji i gbe, ati pe ki wọn lọọ wa ilaji miliọnu naira wa, ti wọn ba fẹ ki wọn fi i silẹ.

Ọkunrin to pe ara rẹ ni ajinigbe yii fun wọn ni  nọmba ile-ifowopamọ ti wọn yoo san owo naa si. Orukọ to si wa nibe ni: Adisa Damilọla, ẹni to jẹ ọrẹ fun ololufẹ Suluka Abimbọla.

Abutu sọ pe eyi lo fa a tawọn fi taari ọrọ naa si ẹka ọtẹlẹmuyẹ to n gbogun ti awọn ajinigbe, ti wọn si bẹrẹ iwadii lori rẹ.

Alukoro ni bi wọn ṣe mu ẹni to ni nọmba ifowopamọ naa tan lo mu awọn ọlọpaa lọ si ileetura kan ti wọn n pe ni Alex Grace Hotel, to wa ni adugbo Housing, niluu Ado-Ekiti, nibi ti wọn ti mu Suluka Abimbọla ati ololufẹ rẹ, Oluwaṣeun Ọlajide, nibi ti wọn fara pamọ si. Bakan naa ni wọn tun fi pampẹ ofin mu Adefọlaju Caleb ti wọn jọ fi ara pamọ si ile-itura naa.

Awọn ọlọpaa sọ pe nigba ti wọn n fi ọrọ wa Suluka Abimbọla lẹnu wo, o jẹwọ pe loootọ loun ati ololufẹ oun ati awọn ọrẹ rẹ meji miiran ti wọn mu lori ẹsun naa jọ gbimọ-pọ lati ji ara awọn gbe lati gba owo lọwọ awọn obi oun. Ki oun le ri owo ti oun yoo fi lọ si ipinlẹ Ọṣun, nibi ti oun ti lero lati kọ iṣẹ ere ori itage.

O fi kun un pe oun ṣe eleyii lati ta ko igbesẹ awọn obi oun pe ki oun lọọ kọ iṣẹ iṣegun oyinbo

Kọmiṣanna ọlọpa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Tunde Monayo, fi aidunu rẹ han si ọrọ naa, o ṣalaye pe ole jija ati jibiti ti pọ ju laarin awọn ọdọ ati ọmọde ni ipinlẹ ọhun.

Kọmiṣanna naa loun ti paṣẹ pe ki wọn bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa, ki wọn si ko awọn ọdaran naa lọ si ile-ẹjọ fun ijiya to peye.

Leave a Reply