Abiọna lu oyinbo ni jibiti, wọn ti sọ ọ sẹwọn ọdun meji n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ọdaran kan, Abiọna Akinyẹmi Festus, tọwọ EFCC tẹ laipẹ yii fẹsun jibiti ori ẹrọ ayẹlujara nile-ẹjọ to n mojuto awọn iwa ọdaran to da yatọ, Special Offences Court, to fikalẹ sagbegbe Ikẹja, niluu Eko, ti ju sẹwọn ọdun meji gbako.

Adajọ Oluwatoyin Taiwo lo paṣẹ naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Ọọfiisi ajọ EFCC to wa niluu Ilọrin lo ṣewadii ọdaran naa lẹyin ti ileeṣẹ to n gbogun tiwa ọdaran nilẹ okere, Federal Bureau of Investigations, FBI, fiwe ranṣẹ si orilẹede Naijiria lati fi ọrọ rẹ to ajọ to n gbogun tiwa ọdaran nilẹ wa leti.

Ninu iwe ti FBI kọ ranṣẹ lọjọ kẹwaa, oṣu keje, ọdun 2019, ni wọn ti rọ EFCC lati tọpinpin Abiọna nitori bo ṣe lu awọn oyinbo ni jibiti.

Abiọna to n pe ara rẹ ni (Ella Jones), lo wọ owo to le ni miliọnu marun-un naira, N5, 950, 000, lati inu akanti awọn oṣiṣẹ-fẹyinti kan tileeṣẹ adojutofo nilẹ Amẹrika n mojuto.

Nigba tọwọ tẹ ẹ, o jẹwọ fawọn EFCC ati ile-ẹjọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun naa.

Adajọ Taiwo paṣẹ pe ki ọdaran naa lọọ ṣẹwọn ọdun meji tabi ko san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un mẹta naira, #600,000, owo itanran.

Ile-ẹjọ tun ni ki ọkunrin naa da gbogbo owo to ji naa pada fun ileeṣẹ to ni i.

 

Leave a Reply