Abiru ki leleyii, agbebọn yinbọn pa ọlọpaa mẹrin lẹnu iṣẹ

Adewale Adeoye

Mẹrin lara awọn ọlọpaa kan ti wọn n ṣiṣẹ ilu lọwọ lagbegbe Ozalla, nijọba ibilẹ Nkanu, nipinlẹ Enugu, ni awọn agbebọn kan ti yinbọn pa danu bayii. Iṣẹlẹ ọhun waye laaarọ kutukutu ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

ALAROYE gbọ pe awọn ọlopaa kan ni wọn wa loju titi marosẹ kan to wa ni Ozalla, nijọba ibilẹ Nkanu, wọn n yẹ awọn mọto ti wọn ko niwee wo ni, bẹẹ ni awọn kan lara wọn n yẹ inu mọto wo boya awọn kan gbe ẹru to lofi sofin ninu awọn dẹrẹba mọto to n kọja lọjọ ọhun. Ṣugbọn lojiji ni awọn oniṣẹ ibi naa kọju ibọn si wọn, ti wọn si yinbọn pa mẹrin danu lara wọn. Yatọ sawọn ọlọpaa naa ti wọn pa, ṣe ni wọn tun jo mọto ijọba kan tawọn ọlọpaa naa gbe lọ sibi iṣẹ naa gburugburu lọjọ yii.

Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti sọ pe awọn maa too bẹrẹ iwadi nipa iṣẹlẹ ohun, tawọn si maa fọwọ ofin mu awọn afurasi ọdaran to ṣiṣẹ ibi naa laipẹ.

Leave a Reply