Abiru ko lẹtọọ lati dije ninu atundi ibo aṣofin Eko-PDP

Jide Alabi

Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP si ipo ọmọ ileegbimọ aṣofin agba lati ẹkun Ila Oorun Eko, Lagos East, Babatunde Gbadamọsi, ati ẹgbẹ oṣelu rẹ ti rọ ile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko lati fofin de oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Tokunbọ Abiru, lati ma ṣe kopa ninu atundi ibo naa to yẹ ko waye ni ọgbọn ọjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ṣugbọn ti wọn ti sun un siwaju,

Ẹsun to fi kan an nipasẹ agbẹjọro rẹ, Ẹbu-Olu Adegboruwa, ni pe kaadi idibo meji loun nikan ni, nitori ko wa lati ibi kankan ninu awọn ijọba ibilẹ to wa labẹ ẹkun Ila-Oorun ti eto idibo naa yoo ti waye.

Ọkunrin naa ni o ti kọkọ dibo ni agbegbe mi-in tẹlẹ, ko too tun waa sọ pe lati ẹkun Ila-Oorun loun ti wa lai jẹ pe o ṣe ayipada ati iforukọ silẹ kaadi rẹ lati ipasẹ ajọ eleto idibo si ibi to ti feẹ dije yii.

Nidi eyi, Babatunde ni niṣe lo yẹ ki wọn yọ orukọ rẹ ati ẹgbẹ rẹ, APC, kuro ninu awọn olukopa.

 Ṣugbọn agbẹjọro rẹ, Kẹmi Pinheiro, ti ni awawi ti ko lẹsẹ nilẹ labẹ ofin ni ẹgbẹ PDP n funka mọ, nitori gbogbo ohun ti wọn n sọ naa ko to ohun ti wọn le tori rẹ sọ pe ki onibaara awọn ma kopa ninu eto idibo naa.

 Tẹ o ba gbagbe, aaye naa ṣofo latari iku Bayọ Ọṣinọwọ to ti wa nibẹ tẹlẹ to ku ni ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹfa, ọdun yii.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii ni adajọ sun igbẹjọ naa si.

 

Leave a Reply