Aburo fẹẹ ṣupo ẹgbọn ẹ, lawọn ọmọ oloogbe ba ṣa a ladaa yannyanna ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Babbi Aliyu fẹẹ supo iyawo ẹgbọn rẹ, Alhaji Bello to ti doloogbe niluu Ikoroku Kaiama, nijọba ibilẹ Kaiama, ipinlẹ Kwara, ti ọrọ naa si pada ja si itajẹsilẹ nigba ti awọn ọmọ oloogbe yari pe Aliyu lọwọ ninu iku baba awọn, tawọn o si ni i gba ko su iya awọn lopo.

ALAROYE gbọ pe gaa awọn Fulani to wa ni Ikoroku Kaiama, ni wahala naa ti bẹ silẹ nigba ti aburo oloogbe Aliyu n gbiyanju lati fẹ iyawo ti ẹgbọn rẹ fi saye lọ, ni awọn ọmọ ba yari pe ko si ohun to jọ ọ, latari pe wọn ni o lọwọ ninu bi baba awọn ṣe dagbere faye. Niṣe lawọn ọmọ yii ṣa Aliyu ni sakuṣaa ni gbogbo imu ati ori, ti ẹjẹ si n san bii agbara ojo.

Agbẹnusọ ajọ ẹṣọ alaabo (NSCDC), ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afolabi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ajọ awọn lo gba arakunrin ọhun silẹ ti ko jẹ ki itajẹ silẹ naa ju bẹẹ lọ laarin awọn mọlẹbi.

Afọlabi ni ẹsun ti wọn mu wa si ileesẹ ajọ NSCDC to wa ni Kaiama, ni pe nigba ti ọkunrin kan to n jẹ Alhaji Bello ku, ni aburo rẹ, Aliyu, fẹ maa fẹ iyawo to fi silẹ, ṣugbọn awọn ọmọ Bello fariga pe awọn o ni i fara mọ ọn tori pe o lọwọ ninu iku baba awọn, eyi lo mu ki wọn lọọ mu ada, ti wọn si ṣa Aliyu ṣakaṣaka.

Wọn sare gbe Aliyu lọ sileewosan ijọba to wa ni Kaiama, sugbọn nigba ti ipa wọn ko ka a, wọn ti pada gbe e lọ si ile iwosan ọgba Fasiti Ilọrin, fun itọju to peye, wọn si ti mu awọn to ṣa a ladaa fun iwadii.

 

Leave a Reply