Aburo ọkọ Tọpẹ Alabi ni: Ki i ṣe pe ẹgbọn mi ko fẹẹ tọju ọmọ ẹ, Tọpẹ lo gbe e sa fun un

*Nigba ti fiimu rẹ bẹrẹ si i ta ni ko waa gbowo lọwọ rẹ mọ n’Idumọta

Bo tilẹ jẹ pe titi di ba a ṣe n sọ yii, gbajumọ akọrin ẹmi ilẹ wa nni, Tọpẹ Alabi, ko ti i sọ ohunkohun lori wahala to n lọ laarin oun ati ọkọ to kọkọ fẹ to bi ọmọbinrin kan ti wọn n pe ni Ayọmikun fun pẹlu bi baba ọmọ naa ṣe fẹsun kan an pe o n gbe ọmọ naa sa fun oun, o si tun yi orukọ rẹ si ti ọkọ to ṣẹṣẹ fẹ. Ṣugbọn ọrọ naa ti di egbinrin ọtẹ bayii, bi wọn ṣe n pa ọkan ni omi-in n ru, ko si jọ pe ọrọ naa yoo pari bọrọ. Eyi ko sẹyin bi ọkunrin kan ti ko darukọ ara rẹ, ṣugbọn to jẹ aburo si ọkọ akọfẹ Tọpẹ yii, iyẹn Mayegun Oyegoke, ti wọn tun n pe ni Ọlaoye Ventures.

Ọkunrin naa lo kọ awọn ọrọ aṣiri kan si ori ikanni ayelujara rẹ lọsẹ to kọja. O ni ki i ṣe pe oun gbe igbesẹ yii lati ba Tọpẹ lorukọ jẹ, tabi lati ba iṣẹ iranṣẹ rẹ jẹ, o ni oun ṣe bẹẹ lati tan imọlẹ si ọrọ naa, nitori ọpọ awọn ti wọn n sọ ohun ti wọn ko mọ nipa ajọṣepọ to wa laarin ẹgbọn oun ati Tọpẹ.

Bẹẹ lo ni igbesẹ yii di dandan nitori bi awọn kan ṣe n tabuku ẹgbọn oun, ti wọn si n sọ pe nitori pe ọmọ naa ti dagba bayii to fẹẹ gba ọmọ naa lo ṣe pariwo sita. O ni ọrọ ko ri bẹẹ rara.

Ọkunrin yii ni nitori akọroyin ori ẹrọ ayelujara to gbe ọrọ naa jade, to si sọ ọ bii pe ọmọ ale ni ọmọ naa lo jẹ ki oun fẹẹ sọrọ, nitori ọdọ ẹgbọn oun yii loun gbe, ọpọlọpọ ohun to si ṣẹlẹ lo ṣoju oun, ti oun si ni ẹri lọwọ lati gbe e lẹyin paapaa.

Eyi ni alaye ti ọkunrin naa ṣe sori ikanni ayelujara rẹ.

‘‘Emi ni aburo si Baba Ayọmikun, (ọmọ Tọpẹ Alabi), a ko le maa dahun si gbogbo ohun ti awọn eeyan n sọ lori ọrọ yii nitori niṣe lo maa di ariwo, to si maa da bii pe niṣe ni a n wọna lati ba iṣẹ orin ti Tọpẹ Alabi n ṣe jẹ.

‘‘Ṣugbọn imọran to fun Ayọ lati lọ sori ẹrọ agbọrọkaye lati sọrọ lai beere bi akọroyin ori ẹrọ ayelujara to gbe iroyin naa ṣe ri i maa ṣi oju ọgbẹ to ti n san tẹlẹ silẹ fun awọn obi ọmọ yii mejeeji, ti onikaluku ti gbagbe ohun to ti ṣẹlẹ tẹlẹ.

‘‘Ohun to hu ọrọ yii jade ni bi wọn ṣe fẹsun kan Ayọmikun pe ọmọ ale ni, eyi lo mu ki ẹgbọn mi jade pe oun ni baba rẹ, oun ko si le sẹ́ pe oun kọ loun bi i.

‘‘Ti akọroyin ori ẹrọ ayelujaara kan ba waa fẹ ẹ loju lati fi han gbogbo aye, nibo lo ti waa kan bọọda mi, nibo lo ti jẹ ẹjọ rẹ?

‘‘Yara kan naa ni mo n gbe pẹlu ẹgbọn mi yii ni ile ta a gbe ni Oguntolu, ni Onipaanu, lọdun naa lọhun-un.  Mo le ṣalaye ti ko ruju nipa bi awọn mejeeji ṣe pade, ati bi Tọpẹ ṣe gbakoso ohun gbogbo, ti wọn si jọ n gbe bii tọkọ-taya.

‘‘Ẹgbọn mi ṣetọju Tọpẹ daadaa ni gbogbo igba to fi wa ninu oyun, titi to fi bimọ. Koda, niṣe ni wọn ṣekomọ ọmọ naa rẹpẹtẹ, nitori wọn pe olorin to waa kọrin nibi ikomọ Ayọmikun, gbogbo awọn to si lorukọ daadaa ti wọn n ta fiimu, ti wọn si n gbe awọn oṣere jade ti wọn wa ni Idumọta nigba naa lo wa nibi ayẹyẹ ikomọ yii. Ẹ  lọọ beere daadaa, ko sẹni ti ko mọ itan Ọlaoye ati Tọpẹ laarin awọn makẹta to n ta fiimu yii.

‘‘Njẹ eyin mọ bi Sọji Alabi ṣe jẹ si Tọpẹ nigba to ṣi wa lọọdẹ bọọda mi? Njẹ ẹyin mọ iye igba ti mo maa wa si Eko lati ileewe, ti mo maa ba Sọji ninu ile ẹgbọn mi pẹlu Tọpẹ nikan? Ohun ti ẹgbọn mi si maa n ṣe nigba naa ni lati fun mi ni igbati olooyi, ti yoo si lu mi gidigidi pe mo n sọ isọkusọ nipa iyawo oun ti mo ba sọ ipo ti mo ba Sọji ati Tọpẹ fun wọn. Ohun ti wọn maa n sọ fun mi nigba naa ni pe ko si ohun to pa Tọpẹ ati Sọji pọ, pe produsa Tọpẹ ati amoju ẹrọ rẹ ni.

‘‘Hummmm, afigba ti Tọpẹ ko jade nile pẹlu ọmọ kekere naa nigba ti ọmọ naa ko ti i pe ọdun kan, igba yii ni oye gbogbo ọrọ naa too ye ẹgbọn mi. Njẹ ẹ mọ pe niṣe ni Tọpẹ sọ ẹgbọn mi di onigbese nigba to lọ pẹlu bo ṣe ko fiimu ati orin rẹ ti ẹgbọn mi ṣonigbọwọ lọ?

‘‘Ẹ jẹ ki n sọ eleyii fun yin, mo si pe Tọpẹ Alabi nija lati jade sita ko waa sọ pe ko ri bẹẹ, ma a waa pe awọn mejeeji tọrọ kan sita pe ki wọn waa koju ara wọn, nigba yii ni ma a waa tu awọn aṣiri kan. Ọdun 1998 ni wọn bi ọmọ yii, ọdun 1999 ni Tọpẹ kuro nile ẹgbọn mi, o si gbe ọmọ naa lọ sọdọ awọn obi rẹ ni Mafoluku, Oshodi, ti wọn n gbe nigba naa.

‘‘Mi o le ka iye igba ti mo lọọ ṣe abẹwo sọmọ naa nigba to wa nileewe jẹle-o-sinmi. Koda, aburo mi to n jẹ Fẹmi toun naa n gbe lọdọ ẹgbọn mi paapaa maa n lọọ bẹ ọmọ yii wo pẹlu aṣọ ọdun Keresi, awọn ẹbun loriṣiiriṣii atawọn nnkan mi-in ti ọmọ yii nilo la maa n ko lọ sọdọ mama Tọpẹ ti wọn n tọju ọmọ naa daadaa nigba ti mo n sọ yii.

‘‘Mo ranti asiko kan ti mo lọọ ṣe abẹwo si ọmọ naa ti Iya Tọpẹ fi esi idanwo ọmọ naa han mi pe o mọwe daadaa, o si n ṣe daadaa nileewe.

‘‘Bẹẹ ni Tọpẹ maa n wa si Idumọta lasiko naa lati waa gbowo lọwọ ẹgbọn mi fun itọju ọmọ yii. Afi nigba ti kasẹẹti rẹ to ṣe, boya ẹlẹẹkeji tabi ikẹta to pe ni ‘Oore ti o Common’ ta daadaa, to si rowo nibẹ ni ko wa mọ.

‘‘Lẹyin ti aye rẹ yipada, to bẹrẹ si i rowo, ti okiki naa si tẹle e, o gba ọmọ naa kuro lọwọ iya rẹ, o gbe e lọ sile ọkọ to ṣẹṣẹ fẹ, nigba yẹn la si dẹkun wiwa ọmọ naa lọ.

‘‘Ọpọ igba ni ẹgbọn mi maa n pe e pe awọn feẹ ri ọmọ naa, o le ni ọwọ oun di, tabi ko ni oun ki i gbele, oun ko si ni Naijiria. Bi Tọpẹ yoo ṣe maa fonii donii, fọla dọla, fun wa niyi ta a ba ni ko gbe ọmọ naa wa, ti ko ni i gbe e wa.

‘‘Ẹgbọn mi naa ti fẹyawo o, o si ti bi awọn ọmọ, bẹẹ lo ti gbagbe iṣẹlẹ to ti ṣẹlẹ sẹyin. Ṣugbọn mi o ro pe ẹni ti ori rẹ pe kan yoo gba ọkunrin kan nimọran pe ko maa lọ sile ọkọ obinrin to kọ ọ silẹ nitori pe o fẹẹ ri ọmọ rẹ to wa nibẹ.

‘‘Ka waa lọ si ọdun 2018, nigba ti Tọpẹ ṣe ọjọọbi to ṣe ifọrọwerọ pẹlu iweeroyin ‘The Punch’, nibi ti Tọpẹ ti sọ pe wundia loun, oun ko mọ ọkunrin kankan titi ti oun fi fẹ Sọji Alabi, nibi ti wahala ti n bẹrẹ diẹdiẹ niyi, ti ọrọ ta lo lọmọ si fi waye nigba ti awọn eeyan bẹrẹ si i gbe e kiri pe Sọji Alabi lo ni ọmọ ti Topẹ Alabi, eyi ni awọn to mọ nipa ọrọ wọn fi n sọ pe ọmọ ale ni Ayọmikun. Eyi lo mu ki ẹgbọn mi kọ awọn ọrọ kan sori ikanni Instagraamu rẹ lati fidi otitọ mulẹ nigba ti ọmọ naa ṣe ọjọọbi ogun ọdun to dele aye.  O fi ọrọ yii kan naa ranṣẹ si Tọpẹ, o si fi ranṣẹ si Ayọmikun paapaa.

‘‘Ki i ṣe pe ẹgbọn mi sọ pe oun fẹẹ gba ọmọ naa lati maa tọju bayii, tabi pe o ṣe eleyii lati le waa jokoo gẹgẹ bii baba lasiko ti ọmọ naa ba ṣe igbeyawo, gẹgẹ bi awọn akọroyin ori ẹrọ ayelujara kan ṣe n gbe e kiri.

‘‘Lẹyin ti ọmọ yii ṣe ọjọọbi ogun ọdun laye, lara igbesẹ ti ẹgbọn mi gbe lati fopin si awuyewuye yii ni bo ṣe pe Tọpẹ Alabi, to si beere lọwọ rẹ pe ki ni idi ti o fi yi orukọ ọmọ naa pada si ti ọkọ rẹ. Ṣe o ṣe eyi lati ma jẹ ki awọn eeyan mọ iru eeyan to jẹ tẹlẹ ni abi bawo? Ipade ti mo n sọ yii, awọn eeyan nla nla to n gbe fiimu jade ati awọn makẹta lo ṣeto ipade naa labẹ idari Alaaji Wasiu ti wọn n pe ni Wastayos Films ati Alaaji Iṣọla Saheed ti wọn n pe ni Isolak Films ni Arena, ni Oshodi. Emi naa wa nikalẹ lọjọ naa, mo si gba ohùn gbogbo ọrọ ta a sọ nibẹ silẹ. Koda, Tọpẹ Alabi gan-an sọ lọjọ naa pe a le gba ohun silẹ lori gbogbo ohun ta a sọ. Tọpẹ ni ohun kan toun mọ ni pe Ọlaoye ko ṣe aidaa kankan si ohun, bẹẹ ni ko si ro ibi si oun, pe oun ko si sọ ohun ti ko dara nipa rẹ fun Ayọmikun. O ni ti ohunkohun ba tilẹ wa, oun Tọpẹ loun ṣẹ Ọlaoye, oun si ṣetan lati tọrọ aforiji lọwọ rẹ.

‘‘O ni idi ti oun fi ni lati yi orukọ ọmọ naa pada si ti ọkọ ti oun ṣẹṣẹ fẹ ni pe lọpọ igba nigba yẹn, oun maa n rin irinajo lati lọọ kọrin loke okun, oun si maa n ni wahala ti oun ba fẹẹ mu ọmọ naa lọ nitori wọn maa ni ki oun lọọ gba iwe iyọnda wa lati ọdọ baba ọmọ naa, ṣugbọn ko le baa rọrun fun oun lati lọ si irinajo pẹlu rẹ ati lati gba iwe irinna fun un loun ṣe yi orukọ rẹ pada. O ni oun ko ṣe eleyii lati ma jẹ ki ọmọ naa mọ itan baba to bi i.

‘‘Nibi ta a wa lọjọ naa ta a ti n sọrọ lo ti fun wa ni nọmba ọmọ naa,  emi ati ẹgbọn mi si ba a sọrọ lọpọ igba, ṣugbọn ko jọ pe aarin awọn mejeeji lọ gaara.

‘‘Awa la sọ fun ẹgbọn wa pe ki wọn tẹ ọrọ naa jẹẹjẹ, ki wọn si ma sọ pe awọn maa sun mọ ọmọ naa lasiko yii nitori awọn eeyan le sọ pe o fẹẹ lo ọrọ naa lati tu aṣiri awọn ohun to ti ṣẹlẹ laarin oun ati iya ọmọ naa ti ko han si ọpọ eeyan ni. O waa jẹ ohun iyalẹnu fun mi nigba ti mo bẹrẹ si i ri ọrọ oriṣiiriṣii ti awọn ti ko mọdi ọrọ, ti wọn ko mọ bi ọrọ ṣe jẹ, n sọ kaakiri.

‘‘Awa ko gba a lero lati wa iṣubu ẹnikẹni, gbogbo wa la ni awọn ohun ta a ti ṣe sẹyin. Ohun to ba si ti waye sẹyin, ẹyin naa lo yẹ ko wa, ko si sẹni to n gbero lati gba ọmọ kan tabi ṣe ohunkohun. Ohun ti ẹgbọn mi ṣe ni lati ṣalaye, ko si jẹ ki akọroyin ori ẹrọ ayelujara naa mọ pe ọmọ oun ki i ṣe ọmọ ale pẹlu bo ṣe n jẹ orukọ ọkunrin mi-in, ti wọn ko jẹ ko maa jẹ orukọ baba to bi i gan-an.

‘‘Awa ti sọ ohun to kan wa, iyẹn naa ni ẹni to bi ọmọ yii ati ẹni to ni in, ẹni to ba si wu ọmọ naa lo le pe ni baba rẹ, ko si ẹni ti eleyii maa bi ninu, nitori a mọ ẹjẹ to wa lara rẹ.

‘‘Idile to ti wa jẹ idile lati ilu Ọwọ, nipinlẹ Ondo, nigba to si jẹ pe ipinlẹ Kogi ni Sọji Alabi ti wa ni tirẹ, ohun to si daju ni pe ‘Funtọ’ ni ọmọ to n tọju yii, ti ohunkohun ko si gbọdọ ṣẹlẹ si i.

‘‘Ootọ ti ko ṣee yipada ni eleyii, bi gbogbo ọrọ si ṣe jẹ yoo tun ye onikaluku si i nigba to ba ya.’’

Ohun ti ọkunrin yii kọ niyi, eyi si jẹ ki awọn oloye sọ pe ko jọ pe ọrọ yii yoo tan nile bọrọ pẹlu awọn aṣiri to n tu jade yii.

AKEDE AGBAYE tun pe ọkunrin to fẹsun kan Tọpẹ Alabi lati gbọ ọrọ lẹnu rẹ, ṣugbọn pipa ni foonu re wa titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii, Bakan naa si lọro ri pẹlu foonu Tọpe, oun naa pa foonu re ni.

One thought on “Aburo ọkọ Tọpẹ Alabi ni: Ki i ṣe pe ẹgbọn mi ko fẹẹ tọju ọmọ ẹ, Tọpẹ lo gbe e sa fun un

Leave a Reply