Ada yanran-yanran ni wọn ba lọwọ Joshua atawọn ọrẹ ẹ ti wọn jọ n ṣẹgbẹ okunkun l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 

 

 

 

 

Akolo awọn ọlọpaa ọtẹmuyẹ to wa ni Panti, Yaba, nipinlẹ Eko, ni ni awọn afurasi ọdaran mẹta yii, Joshua Ubokuho, Emmanuel Yusuf ati Adewale Hammed, wa lọwọlọwọ yii, ibẹ ni wọn ti n ran awọn agbofinro lọwọ ninu iṣẹ iwadii wọn, wọn ni afurasi ọdaran ni wọn, ati pe wọn n ṣe ẹgbẹ buruku tijọba o fọwọ si, ẹgbẹ okunkun.

 

Hakeem Odumosu, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, funra ẹ lo sọrọ yii lọjọ Abamẹta, Satide yii, lọfiisi rẹ n’Ikẹja, lasiko ipade pataki kan to ṣe lori eto aabo, o ni agbegbe Lẹkki, lọna Ajah, lọwọ awọn agbofinro ti ba awọn mẹtẹẹta.

 

“Awọn ọlọpaa lati teṣan Ẹlẹmọrọ, ni Lẹkki, ni wọn mu awọn afurasi ọdaran yii laduugbo Imalete Alaafia, n’Ibẹju Lẹkki. Nigba ti wọn mu wọn, wọn ba awọn oogun abẹnugọngọ lapo wọn atawọn nnkan ija mi-in, bẹẹ ni wọn ba ada aṣiya tuntun yanran-yanran lọwọ wọn, wọn fi ọda kọ “zero 4” sara awọn ada naa, orukọ ami ẹgbẹ okunkun wọn ni. A ti tubọ n ṣe iwadii si i nipa ami ti wọn kọ yii, a si ti tun ri awọn ootọ kan mu jade. Bakan naa lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ bọọsi kan ti wọn n lo,” bẹẹ ni Odumosu sọ.

 

Odumosu tun ṣalaye pe awọn ti taari awọn afurasi naa sakata awọn ọtẹlẹmuyẹ. O ni iṣẹ ti n lọ lọwọ lati tubọ gbọn gbogbo ibuba tawọn janduku atawọn ẹlẹgbẹ okunkun yii n fara pamọ si lawọn agbegbe bii Lẹkki, Ajah, Badore, Ṣangotẹdo, Ẹlẹmọrọ, Ibẹju-Lẹkki, Akodo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

O lawọn ti ṣeto ipade mi-in, eyi to maa waye lọjọ kẹsan-an, oṣu yii, ni gbọngan POWA, n’Ikẹja, lati tubọ jiroro lori awọn ọna tuntun ati ọgbọn-inu ti wọn fẹẹ maa lo lati le gba iwa janduku, iwa ọdaran wọlẹ patapata nipinlẹ Eko.

 

Ni ti awọn tọwọ ba yii, Odumosu ni awọn maa sin wọn dele-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply