Adajọ ṣi ade danu lori awọn baalẹ Ibadan, o ni wọn ko lẹtọọ sipo ọba

Ọlawale Ajao, Ibadan
Adajọ agba ipinlẹ Ọyọ, Onidaajọ Munta Abimbọla, ti paṣẹ pe ki gbogbo awọn Baalẹ atawọn Mọgaji ti wọn gba agbega lọjọsi pe ki onikaluku wọn wabi tọju ade ẹ pamọ si nitori ofin ko fara mọ ọba ti wọn jẹ.
Ninu idajọ ẹ lori ẹjọ tawọn baalẹ atawọn mogaji mẹrinlelọgbọn (34), ti wọn gba agbega ọhun pe, Onidaajọ Abimbọla paṣẹ pe ki awọn eeyan naa pada sipo ijoye lasan ti wọn wa tẹlẹ kia.
Ta o ba gbagbe, lọkọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 2017, nijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ ìṣàkóso Oloogbe Abiọla Ajimọbi, fi awọn àgbààgbà ijoye atawọn baalẹ ilẹ Ibadan jọba, eyi to mu ki awọn ọba alade pọ niluu Ibadan bii koriko.
Igbesẹ yii ni Osi Olubadan ilẹ Ibadan, Sẹnitọ Rashidi Adewọlu Ladọja, ta ko to fi pe ijọba atawọn ọba naa lẹjọ, o ni kile-ẹjọ ṣi ade ori wọn danu, nitori ona ti wọn gba jọba ko ba ofin oye jijẹ nilẹ Ibadan mu.
Bi Ladọja ṣe wi gan-an nile-ẹjọ ṣe. Eyi lo mu ki awọn olujẹjọ naa tun gba kootu lọ, wọn ni idajọ ọhun ko ba awọn lara mu, ki ile-ẹjọ fi awọn sipo ọba ti awọn wa jẹẹjẹ awọn.
Ẹjọ ọhun l’adajọ agba ipinlẹ yi danu l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun 2022 yii, to ni ẹjọ ti awọn ijoye ohun pe ko lẹsẹ nilẹ, o yi ẹjọ naa danu, o si fofin de wọn lati ma de ade tabi pera wọn lọba.

Leave a Reply