Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke

Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, ti fipo silẹ gẹgẹ bii ọga awọn adajọ nilẹ wa. Idi to fi ṣe bẹẹ gẹgẹ bo ṣe sọ fun ileeṣẹ tẹlifiṣan ARISE ko sẹyin aiyaara.

Ṣugbọn awọn to mọ bo ṣe n lọ sọ pe awọn ẹsun ọlọkan-o-jọkan ti awọn adajọ ẹgbẹ rẹ fi kan an wa lara idi to fi fẹẹ fipo silẹ.

Lati bii ọjọ mẹta ni fa-a-ka-ja-a ti n waye laarin adajọ agba yii atawọn adajọ ile-ẹjọ giga ilẹ wa lori awọn ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin naa pe ko tọju awọn adajọ, bẹẹ ni ko mọ nipa isakoso, bẹẹ ni wọn ni awọn ohun to tọ si awọn adajọ naa, awọn mọlẹbi rẹ lo n taari anfaani naa si.

Awọn adajọ yii ni awọn mọto to ti di jẹkurẹdi lawọn fi n ṣiṣẹ, bẹẹ ni ko pese ilegbee fawọn, wọn ni ọsibitu tawọn adajọ n lo ko ni oogun atawọn ohun to yẹ ko ni, bẹẹ ni daku-daji ina ijọba n yọ awọn lẹnu lati ṣiṣẹ awọn, ọkunrin yii ko si ri ohunkohun ṣe si eleyii.

Wọn fi kun un pe bo tilẹ jẹ pe awọn ileeṣẹ amunawa ti fi kun owo ti wọn n gba lori owo ina, wọn ni owo ti adajọ agba n fun awọn ko le si iye to n fun awọn tẹlẹ lati bii ọdun mẹrin sẹyin, bẹẹ ni ko si intanẹẹti tawọn le fi maa gbe nnkan sori ayelujara. Wọn fi kun un pe o gbegi di gbogbo ipade tawọn maa n lọ nilẹ okeere lati fi imọ kun imọ atawọn nnkan mi-in.

Iwe yii ni wọn kọ si adajọ agba, ṣugbọn ti ọkunrin naa fesi pe wọn gbọdọ maa ri awọn adajọ ni, wọn ko gbọdọ maa gbọ ohun wọn. Eyi tumọ si pe ko yẹ ki awọn adajọ yii maa sọrọ sita bi wọn ṣe sọ yii.

Eyi lo jẹ ki awọn adajọ agba yooku maa pariwo pe afi ki ọkunrin naa kuro nipo gẹgẹ bii olori awọn. Bakan naa ni ẹgbẹ awọn agbẹjọro nilẹ wa (NBA), ti lọ si ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lati pẹjọ ta ko airi itọju to yẹ ti awọn adajọ ilẹ wa n koju lọwọ ọga wọn yii.

Leave a Reply