Aderounmu Kazeem
Adajọ agba lorilẹ-ede yii, Tanko Muhammad, naa ti ko arun koronafairọọsi.
Ọkan lara awọn adajọ nile-ẹjọ to ga julọ nilẹ wa, Adajọ Ibrahim Saulawa, lo sọrọ yii nibi apejọ kan niluu Abuja, loni-in ọjọ Iṣẹgun, Tusidee.
Nibi ti wọn ti n ṣe ifilọlẹ olu-ile ẹgbẹ awọn Amofin ti wọn jẹ Musulumi niluu Abuja ni Adajọ naa ti sọ pe ilu Dubai lọhun-un ni Adajọ Tanko wa bayii nibi to ti n gba itọju.
Nibi ayẹyẹ pataki kan to waye lana-an, ọjọ Aje, Mọnde, ni wọn ti kọkọ ṣakiyesi wi pe ọkunrin naa ko si nile, nibi ti wọn ti bura fun awọn Amofin mejilelaadọrin (72) sipo Amofin agba (SAN).
Adajọ Ọlabọde Rhodes-Vivour, ẹni ti ipo ẹ tun sunmọ Adajọ Tanko nile ẹjọ to ga julọ lorilẹ-ede yii gan-an lo bura fawon amofin agba ọhun.