Adajọ ju aafaa ajanasi ilu Ẹdẹ to lu jibiti miliọnu mẹwaa sẹwọn  

Idowu Akinrẹmi, Ikire

Ajanasi ilu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun, Aafaa Rafiu Inaọlaji, ẹni ọdun marundinlọgọta (55) ati ẹni keji rẹ, Lukman Oloye; ẹni ọdun mejilelaaadọta ni kootu Majisireeti ipinlẹ Ọṣun ti paṣẹ pe ki wọn ṣi wa lọgba ẹwọn ilu Ileṣa na, nitori ẹsun jibiti miliọnu mẹwaa naira ti wọn fi kan wọn.

Usman Hammed Alabi ni wọn ni wọn gba miliọnu mẹwaa naira naa lọwọ ẹ ninu oṣu kọkanla, ọdun 2019, pẹlu ileri pe awọn yoo ko awọn nnkan eelo ikọle to to iye naa fun un, ṣugbọn wọn ko mu ileri ọhun ṣẹ, wọn ko si da owo pada. Yatọ sawọn meji ti wọn n jẹjọ yii, wọn ṣi n wa awọn mi-in ti wọn ni wọn jọ lu jibiti naa.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn yii ni wọn lo ta ko iwe ofin iwa ọdaran ti ipinlẹ Ọṣun n lo, eyi ti wọn ṣe lọdun 2002.

Adajọ D.O Ajiboye ko faaye beeli silẹ fawọn olujẹjọ. O ni ki wọn gbe wọn lọ sọgba ẹwọn Ileṣa, ki wọn wa nibẹ di ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.

Leave a Reply