Adajọ ju Dokita Adekọya sẹwọn ọdun mẹrinla, ọmọ ọdun mẹsan-an lo fipa ba lo pọ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori to fipa ba ọmọọdun mẹsan-an laṣepọ, ile-ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa ni Ring Road, n’Ibadan, ti sọ dokita kan, Ṣeyi Adekọya, sẹwọn ọdun mẹrinla.

Ọmọọdun mẹsan-an pere, Damilọla Ọlawuyi, to wa nileewe alakọọbẹrẹ ọlọdun kẹta l’Adekọya fọgbọn agba tan lọ sinu yara ẹ ninu ile ẹ to wa laduugbo Oke-Ọffa, nitosi Baba-Isalẹ, n’Ibadan.

Lati inu oṣu kẹjọ, ọdun 2015, ti dokita to n ṣewosan fawọn alaisan nilana iṣegun ibilẹ yii ti huwa ọdaran ọhun ni ẉọn ti gbe e lọ si kootu nitori ọjọ kẹrindinlogun, oṣu naa, lo ṣe aṣemaṣe ọhun. Ṣugbọn lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja nidajọ waye.

Nigba to n ṣagbeyẹwo awọn ẹjọ ti wọn ti ro ṣaaju ninu awọn igbẹjọ gbogbo to ti waye, Adajọ kootu ọhun, Onidaajọ Ezekiel O. Ajayi, sọ pe awọn ẹri ti olujẹjọ ati agbẹjọro fihan ni kootu fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni dokita ba ọmọọdun mẹsan-an naa laṣepọ, o si fi kinni nla fa a nidii iya.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Damilọla nikan ṣoṣo lẹlẹrii ta a ni lori ẹjọ yii, o si ṣalaye bi olujẹjọ ṣe huwa ti ko bojumu fun oun. O jẹ ka mọ pe ẹẹmeji lo kọkọ kọwọ bọ oun labẹ ko too fipa ba oun laṣepọ.

Pẹlu ẹri yii atawọn awijare agbẹjọro olupẹjọ, o han daju pe olujẹjọ jẹbi ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.”

O waa sọ dokita naa sẹwọn ọdun mẹrinla pẹlu iṣẹ aṣekara lai fi aaye owo itanran silẹ.

 

Leave a Reply