Adajọ ju Mike sẹwọn ọdun mẹtadinlogun, awọn kan lo lu ni jibiti l’Ode-Irele

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Fun lilu awọn eeyan ni jibiti, Adajọ Ile-ẹjọ giga to wa l’Akurẹ, Onidaajọ Samuel Bọla, ti ju Mike Atẹlẹmọ sẹwọn ọdun mẹtadinlogun.

Jibiti owo to le ni miliọnu mejilelogoji Naira ni wọn lọkunrin naa lu awọn eeyan niluu Ode-Irele, laarin ọdun 2017 sì 2018, nipasẹ ayederu ileeṣẹ ayanilowo fi ṣowo kan to gbe kalẹ.

Ipinlẹ Delta, nibi to lọọ fara pamọ si lọwọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti pada tẹ ẹ, ti wọn si wọ ọ lọ sile-ẹjọ ninu oṣu keji, ọdun ta a wa yii, lori awọn ẹsun mẹrinla tí wọn ka si i lẹsẹ.

Awọn ẹlẹrii bii mejila ni wọn waa jẹrii ta ko o lasiko ti igbẹjọ n lọ lọwọ.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, Onidaajọ Bọla ni awọn ẹri ti agbefọba fi siwaju oun fidi rẹ mulẹ pe loootọ lo jẹbi diẹ ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

O ni ki ọdaran ọhun lọọ fẹwọn ọdun meje jura lori ẹsun gbigbimọ-pọ lọna aitọ, ọdun meje mi-in fun gbigba owo olowo lọna aitọ ati ẹwọn ọdun mẹta fun pipe ara rẹ ni oun ti ko jẹ fawọn eeyan.

Adajọ yii tun ni o gbọdọ da gbogbo owo to ti fọna eru gba lọwọ awọn eeyan padafun wọn kiakia.

Leave a Reply