Adajọ ju ọlọkada to lu ọlọpaa sẹwọn l’Ọsun

Adewale Adeoye

Onidaajọ A. Ayaba, ti ile-ẹjọ Majisireeti kan niluu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, ti ni kawọn ọlọpaa ṣi lọọ ju Ọgbẹni Olaoye Moses sẹwọn kan to wa niluu Ileṣa, titi digba ti igbejọ yoo fi waye nipa ẹjọ rẹ.

ALAROYE gbọ pe ẹsun pe olujẹjọ naa doju ija kọ ọkan lara awọn ọlọpaa ilẹ wa lakooko ti agbofinro naa n ṣiṣẹ ilu lọwọ ni wọn fi kan an, eyi ti wọn sọ pe ofin ilẹ wa fajuro si, ti ijiya nla si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ labẹ ofin.

Ọlọpaa olupẹjọ to foju ọdaran naa bale-ẹjọ, Insipẹkitọ Akintunde Jacob, ni Ọlaoye to jẹ ọlọkada laarin ilu naa koju ọlọpaa kan, Sajẹnti Bankọle Abiọdun, lakooko tiyẹn n ṣiṣẹ sin ilu lọwọ, ti ofin ko si faaye gba a rara.

Agbefọba ni, ‘Iwọ, Ọgbẹni Olaoye Moses, to o jẹ ọlọkada lu ofin irinna ipinlẹ Ọṣun, lọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un ọdun 2023 yii, nipa pe o gbeja ko Sajẹnti Bankọle Abiọdun, ọkan lara ọlọpaa to n dari igboke-gbodo ọkọ lagbegbe Ọta-Efun, nipinlẹ Ọṣun. 

Yatọ si pe o lu ofin irinna ọkọ nipinlẹ naa, o tun yẹpẹrẹ ọlọpaa ọhun lẹnu iṣẹ rẹ, eyi ti ofin ipinlẹ naa si fajuro si gidi, ti ijiya si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ.

Nigba to n dahun si ẹsun ti won fi kan an, olujẹjọ naa loun ko jẹbi awọn ẹsun pẹẹpẹẹpẹ ti wọn fi kan oun rara.

Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Ayaba ko gba beeli ọdaran naa rara, o ni ẹṣẹ to ṣẹ ki i ṣohun kekere, o si paṣẹ pe kawọn ọlọpaa lọọ ju u sọgba ẹwọn Ileṣa. 

Lẹyìn eyi lo sun igbẹjo si ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.

Leave a Reply