Adajọ ju Oni to fipa ba ọmọ ọdun mẹrin lo pọ l’Akurẹ sẹwọn gbere

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ

Ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Modupẹ Oni, ti gba idajọ ẹwọn gbere lati ile-ẹjọ giga kan to wa l’Akurẹ lori ẹsun fifipa ba ọmọọdun mẹrin lo pọ n’Ifọn, nijọba ibilẹ Ọṣẹ.

Ọjọ kẹrinla, osu kẹfa, ọdun 2017, ni iṣẹlẹ yii ti waye, iyawo ọdaran ọhun ni wọn lo fun ọmọdebinrin naa lowo lati lọọ ra kulikuli wa lọṣan-an ọjọ naa, asiko to pada waa jabọ isẹ ti wọn ran an ni Modupẹ ki ọmọ ọlọmọ mọlẹ to si fipa ba a lo pọ.

Lẹyin tọmọ ọhun pada dele, to si royin ohun toju rẹ ri fawọn obi rẹ ni wọn sare mu un lọ sile-iwosan, nibi ti ayẹwo ti fidi rẹ mule pe loootọ ni wọn fipa ba a lo pọ.

Wọn fọrọ yii to awọn ọlọpaa Ifọn leti, lati ibẹ ni wọn si ti fi i ṣọwọ si olu ileesẹ wọn to wa l’Akurẹ fun ẹkunrẹrẹ iwadii.

Lati igba naa ni wọn ti wọ ọkunrin to n siṣẹ panẹ bita yii lọ sile-ẹjọ lori ẹsun meji ọtọọtọ, eyi ti wọn lo tako abala ọtalelọọọdunrun-un din mẹta (357) ati ọtalelọọọdunrun-in din meji (258) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii, Onidaajọ Samuel Bọla ni ki olujẹjọ naa tete maa lọ si ẹwọn gbere niwọn igba ti  gbogbo awọn ẹri ti wọn ko wa sile-ẹjọ ti fidi rẹ mulẹ pe loootọ ni olujẹjọ jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

One thought on “Adajọ ju Oni to fipa ba ọmọ ọdun mẹrin lo pọ l’Akurẹ sẹwọn gbere

Leave a Reply