Adajọ lawọn ọmọ ‘Yahoo’ toun da lẹbi le waa ṣẹwọn wọn lẹyin ti wọn ba ṣetan nileewe giga ti wọn wa

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Nitori ẹsun jibiti lori ẹrọ ayelujara, ile-ẹjọ giga kan to wa niluu Ilọrin, ti paṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, pe ki awọn ọdaran meji kan, Ganiyy Rasaq, akẹkọọ Fasiti Ilọrin, to wa ni ipele kẹta, (300L) ati Ọlakunle Adebisi, akẹkọọ Kwara Poli, ( ND2), lọọ faṣọ penpe roko ọba.

Adajọ Abdulgafar to gbe idajọ naa kalẹ sọ pe, saaju lawọn mejeeji ti gba pe loootọ lawọn jẹbi ẹsun ti ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ajẹbanu, EFCC, fi kan wọn.

O ni lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni aṣoju ajọ EFCC, Ọgbẹni Sẹsan Ọla, gbe awọn ẹlẹrii meji, Dagogo Urowayino ati Shetima Yusuf, wa sile-ẹjọ, lati waa jẹrii ta ko Rasaq ati Adebisi, ti wọn si fidi ootọ mulẹ.

Awọn ẹlẹrii mejeeji si ṣe ẹkunrẹrẹ alaye lori bi awọn ọdaran mejeeji ṣe n lu awọn eniyan ni jibiti lori ẹrọ ayelujara, nipa didibọn bii obinrin, ti wọn si n gba obitibiti owo lọwọ awọn ọkunrin pe awọn nifẹẹ wọn, gbogbo ẹri maa jẹ mi niṣo ni wọn fi han nile-ẹjọ.

Onidaajọ Abdulgafar ti waa gbara le ẹri ti wọn gbe si iwaju rẹ, o ni ki Adebisi lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa, ki Ganiyy lọọ ṣẹwọn oṣu kan pere ninu ọgba ẹwọn Mandala to wa niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

Ṣugbọn adajọ sun ẹwọn awọn mejeeji si ọjọ iwaju, o ni Adebisi le ṣẹwọn rẹ lẹyin ọdun meji ti yoo ti pari eto ẹkọ rẹ nile ẹkọ Kwara Poli, bakan naa, Ganiyy le ṣẹwọn rẹ, lẹyin ọdun kan, nigba ti yoo ti kawe gboye ni Fasiti Ilọrin.

Leave a Reply