Adajọ ni ki wọn dana sun kọmputa ati foonu ti Babatunde fi n lu jibiti

Faith Adebọla

Ọdaran ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Babatunde Samuel, ti di agbalẹ kootu, ọsẹ meji gbako ni yoo si fi gba ilẹ kootu ọhun gẹgẹ bii apa kan sẹria ti ile-ẹjọ da fun un latari iwa lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara, eyi ti wọn n pe ni ‘Yahoo’, to ṣe.
Ile-ẹjọ giga ilu Abuja kan lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii, latari ẹsun ti ajọ to n gbogun ti iwa jibiti nilẹ wa, EFCC, ka si i lẹsẹ, ti olujẹjọ naa si gba pe loootọ loun jẹbi.
Yatọ si ilẹ gbigba, Adajọ kootu naa, Onidaajọ Aliyu Aṣafa, tun paṣẹ pe ki wọn dana sun kọmputa agbeletan, foonu, ẹrọ intanẹẹti ati awọn nnkan eelo gbogbo ti Babatunde fi n ṣe ‘Yahoo’ rẹ.
Ajọ EFCC lo wọ Babatunde lọ sile-ẹjọ nibẹrẹ ọdun yii latari bi wọn ṣe ni o lo ikanni Fesibuuku rẹ lati fi lu jibiti, o purọ pe ẹnjinnia to n ṣiṣẹ gaasi loun, ati pe ọmọ ilẹ China loun, Andy Wong lo loun n jẹ.
Agbẹjọro EFCC, Khalid Sanusi, ṣalaye pe diẹ lo ku ki ọdaran yii ṣe gbaju-ẹ ẹgbẹrun mẹwaa dọla ($10,000) fun oyinbo kan, Karen, to ko sakolo ẹ. Wọn ni iwa to hu yii ta ko isọri okoolelọọọdunrun ati ẹyọ kan ninu iwe ofin iwa ọdaran ilẹ wa.
Lẹyin atotonu tọtun-tosi, agbẹjọro olujẹjọ, Ọgbẹni E. G. Inalegwu, rọ ile-ẹjọ lati ṣiju aanu wo onibaara oun, tori ko si akọsilẹ iwa ọdaran kan nipa ẹ, igba akọkọ to maa huwa aidaa ọhun niyi. O tun ni ki wọn ro ti ọjọ-ori ẹ, ko ma ti kekere w’ẹwọn, ati pe ọkunrin naa ni akọbi mama rẹ, mama naa si ti darugbo, ọsibitu lo wa to ti n gba itọju lọwọ.
Babatunde funra ẹ naa rawọ ẹbẹ si ile-ẹjọ pe ki wọn ṣaanu oun, o ni iṣẹ aje loun wa wa si Abuja, oun o mọ ohun to sun oun de idi iwa ‘Yahoo’ ati jibiti, o loun o ni i ṣe’ru ẹ mọ, ki wọn fi eyi fa oun leti.
Ṣa, Adajọ Shafa ni ki ọdaran yii fi ọsẹ meji gbalẹ kootu lojoojumọ, lati aago mẹjọ si mẹwaa owurọ, ko si tọwọ bọwe adehun pe oun o tun ni i rin ni bebe iwa jibiti fun ọdun meji gbako.

Leave a Reply