Ọgba ẹwọn ti wọn n tọju awọn ọmọ alaigbọran to wa niluu Ado-Ekiti ni Onidaajọ Adekunle Adelẹyẹ ni ki wọn taari ọmọ ọdun mọkanla kan to fipa ba ọmọ ọdun mẹta lo pọ niluu Osi Ekiti, nipinlẹ Ekiti si.
Ninu iwe ẹsun ti wọn ka si ọmọkunrin naa lẹṣẹ, ọgbọnjọ, oṣu karun-un, ọdun 2020, ni ọmọkunrin naa ki ọmọ yii mọlẹ, to si fipa ba a lo pọ, eyi ti ile-ẹjọ ni o lodi sofin to ni i ṣe pẹlu ọrọ ọmọde.
Iya ọmọ naa ti wọn porukọ rẹ ni Elizabeth ṣalaye fun kootu pe ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ni ohun ti ibi ti oun kiri ẹja lọ pada sile, nitori ẹja ni oun n ta.
‘‘Nigba ti mo ri ọmọ mi, mo ṣakiyesi pe ẹjẹ yi asọ rẹ, mo si tun ri i pe atọ ọkunrin wa lara rẹ, nigba ti mo beere ẹni to fọwọ kan an, ọmọ mi nawọn si afurasi yii pe oun lo ṣe oun bẹẹ. Nigba ti mo lọọ ba a ti mo beere lọwọ rẹ, o ni oun ko fọwọ kan ọmọ mi.
‘‘Awọn araadugbo waa jẹrii si i pe awọn ri ọmọ mi lọdọ ọmọkunrin yii to n ba a ṣere. Nigba to ri i pe aṣiri ọrọ naa ti tu lo jẹwọ fawọn ọlọpaa teṣan Ido-Ekiti pe loootọ loun ṣẹ ẹṣẹ naa.’’
Ẹlẹrii meji ni agbẹjọro ijọba, SBJ Bamidele, pe lati kin ọrọ rẹ lẹyin ni kootu. Ninu wọn ni dokita to ṣe afihan ayẹwo ti wọn ṣe nipa ọmọ naa nileewosan, to si fidi rẹ mulẹ pe loootọ ni wọn ti ba a lo pọ.
Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Adelẹyẹ ni alaye agbẹjọro ijọba lori ọrọ naa ko ni ẹja-n-bakan ninu. O ni gbogbo ẹri lo ti fi han pe loootọ ni ọmọkunrin naa huwa ọdaran ti wọn sọ pe o hu.
Ṣugbọn agbẹjọro afurasi yii, Paul Ayantoyinbo, sọ pe ki ile-ẹjọ ṣiju aanu wo ọmọkunrin yii, o ni ọmọde lo ṣe e, nitori ko ti i ju ọmọ ọdun mẹẹẹdogun lọ to fi huwa to hu naa. O ni ki adajọ ṣiju aanu wo o.
Ṣugbọn Adajọ Adelẹyẹ ko gba ipẹ yii, niṣe lo paṣẹ pe ki wọn lọọ fi ọmọkunrin naa si ile awọn ọmọ alaigbọran to wa niluu Ado-Ekiti.