Adajọ ni ki wọn lọọ yẹgi fun Gbenga Aluko l’Ekiti

Aderounmu Kazeem

Ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ekiti, to filu Ado-Ekiti ṣebujokoo ti ni ki wọn lọọ yẹgi fun Gbenga Aluko, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Cherry, titi ti ẹmi yoo fi bọ lara ẹ.
Adajọ ni ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ti ọwọ tẹ yii jẹbi ẹsun iku gẹgẹ bi ofin ipinlẹ Ekiti ṣe la a kalẹ nitori to dara pọ mọ ẹgbẹ okunkun.
Wọn ni lọjọ kẹtalelogun, oṣu ki-in-ni, ọdun 2019, lọwọ tẹ ẹ, ati pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ lo n ṣe, bẹẹ gẹgẹ ni ofin ipinlẹ naa tọdun 2017 sọ pe ẹni tọwọ ba tẹ fun iru ẹsun bẹẹ, pipa ni ki wọn pa a.
Adajọ Abiọdun Adesọdun sọ pe, ‘Ijiya to wa lori ẹsun ti wọn fi kan ọ yii ni wọn yẹgi fun ẹ titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ, ki Ọlọrun forí ji ọ.”
Gbenga Aluko naa ti jẹwọ, alaye to si ṣe ni pe awọn eeyan tawọn naa jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun mi-in loun atawọn ẹlẹgbẹ oun ti pa danu, Mercy lojuna NOVA, Ajagbe ati Mugbagba niluu Ado Ekiti, bakan naa lo jẹwọ pe ọpọ eeyan loun ti lu ni jìbìtì daadaa, bakan naa loun tun maa n ṣe tọọgi fun awọn oloṣelu.
Supreme Eiye Confraternity lo pe orukọ ẹgbẹ okunkun wọn, bakan naa ko darukọ awọn eeyan bii Yemi Effizy, AY Pumping, Wonderful, T Black, Femi atawọn mi in pe awọn jọ n ṣe e ni.

 

 

 

Leave a Reply