Adajọ ni ki wọn lọọ yẹgi fun Rafiu niluu Ẹdẹ lori ẹsun idigunjale

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lori ẹsun idigunjale ati igbiyanju lati paayan, adajọ ile ejọ giga kan niluu Ẹdẹ ti paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun Rafiu Saheed, ẹni ọdun mẹrinlelogoji.

Ọgbọnjọ, oṣu keje, ọdun 2012, ni Rafiu huwa naa niluu Ileefẹ. Agbẹjọro lati ileeṣẹ eto idajọ, Barisita Bankọle Awoyẹmi, sọ ni kootu pe ṣe ni olujẹjọ sọ pe ki Ọlaniyi Ọlayinka to jẹ ọlọkada gbe oun lati ilu Ifẹ lọ sọdọ ẹgbọn rẹ niluu Ipetumodu.

Nigba ti wọn de Ipetumodu, wọn ko ba ẹgbọn Rafiu, lo ba tun sọ pe ki Ọlaniyi gbe oun pada si Ileefẹ. Loju ọna lo ti yọ ọbẹ si ọlọkada, to si fi ge e lọna ọfun.

Lẹyin to ro pe Ọlaniyi ti ku lo gbe ọkada rẹ sa lọ. Nigba ti afẹfẹ fẹ si Ọlaniyi, o dide, o si lọọ fi iṣẹlẹ naa to ọlọpaa leti.

Ọwọ tẹ Rafiu pẹlu ọkada to ji, latigba naa lo si ti wa lakolo ọlọpaa. Sajẹnti Okeniyi Ṣẹgun lati agọ ọlọpaa Ipetumpdu lo ṣaaju awọn ti wọn lọọ fi panpẹ ọba gbe olujẹjọ niluu Ileefẹ.

Ẹlẹri meji atawọn nnkan mi-in ni agbefọba ko silẹ lati jẹrii ta ko Rafiu ni kootu.

Agbẹjọro fun olujẹjọ, Barisita Julie Ọlọrunfẹmi, bẹ kootu lati ṣiju aanu wo o.

Ṣugbọn ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Kudirat Akano sọ pe awọn olupẹjọ ti fidi ẹsun naa mulẹ daadaa, nitori naa, olujẹjọ jẹbi ẹsun mejeeji.

O ran an sẹwọn ọdun mẹrinla lori ẹsun igbiyanju lati paniyan, o si ni ki wọn yẹgi fun un titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ lori ẹsun idigunjale.

Leave a Reply