Adajọ ni ki wọn maa ko Kyari atawọn ọmọọṣẹ rẹ lọ si ọgba ẹwọn Kuje

Ọrẹoluwa Adedeji

Ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja ti paṣẹ pe ki wọn taari Igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa to n ri si awọn ẹsun iwa ọdaran to ba le ju, Abba Kyari, atawọn ọmọọṣẹ rẹ mẹfa ti wọn jọ n jẹjọ ẹsun oogun oloro si ọgba ẹwọn Kuje, niluu Abuja. Kootu kọ lati gba beeli wọn.

Adajọ to n gbọ ẹsun naa, Emeka Nwike lo paṣẹ pe ki ajọ to n ri si gbigbe ati lilo oogun oloro maa ko awọn eeyan naa lọ si ọgba ẹwọn yii lẹyin to kọ lati gba beeli wọn.

Kootu naa sọ pe NDLEA ko awọn ẹri to to siwaju ile-ẹjọ naa lati gbe ẹjọ wọn lẹsẹ pe ki wọn ma gba beeli awọn olujẹjọ naa.

Bakan naa ni kootu kọ lati fun awọn ọmọọṣẹ Kyari, ACP Sunday Ubia, Insipẹkitọ Simeon Agirgba, ati Insipẹkitọ John Nuhu, ASP Bawa James atawọn to gbe oogun oloro ti awọn Kyari lọọ gba lọwọ wọn ni papakọ ofurufu Enugu, Chinbunna Patrick Imeibe, Emeka Alphonsus  Ezenwane.

Adajo Nwike paṣẹ pe ki wọn tete gbọ ẹjọ awọn olujẹjọ naa, to si fi igbẹjọ lori oogun oloro ti awọn Ezewane ati Umeibe gbe si ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹrin ọdun yii.

 

Leave a Reply