Adajọ Okuwobi kilọ fawọn LCC: Ẹ ma jẹ ki n rẹsẹ yin ni too geeti Lẹkki o

Aderohunmu Kazeem

Ko jọ pe ọrọ igbimọ oluwadii to n ri si iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni Lẹkki logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ati ileeṣẹ to n mojuto too geeti Lẹkki, LCC, yoo pari bọrọ bi nnkan ṣe n lọ yii o. Alaga igbimọ naa, Doris Okuwobi ti ni oun ko le fun awọn alaṣẹ too geeti naa ni anfaani lati lọ sibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ gẹgẹ bi ileesẹ naa ṣe n beere fun un, Wọn ni o ṣee ṣe ki awọn ṣi fẹẹ pada lo si Too geeti yii lẹyin tawọn ba wo fidio kamẹra ikọkọ ti wọn gbe wa tan. Bi aọn ba si ti gab wọn laaye lati lọ sibe, o le ṣe idiwọ fun iwadii ti aọn n ṣe.

Agbejọro LCC, Rotimi Seriki  ti n rawọn ẹbẹ si igbimọ naa pe ki wọn fun ileesẹ na lanfaani lati lọ sibẹ, ki wọn le lọọ wo bi adanu to ṣẹlẹ nibẹ ti pọ to, ki awọn ileeṣẹ ma-da-mi-dofo (Insurance) le waa ṣayẹwo ibẹ lati mọ ohun ti wọn ba maa ṣe fun ileeṣẹ yii.

O ni awọn ko ti i ni anfaani lati debe latọjọ ti iṣẹlẹ yii ti sẹlẹ yatọ si ọjọ Ẹti to kọja ti aọn alaṣẹ ileesẹ naa jọ lọ sibẹ pẹlu igbimọ to n gbọ ẹsun isẹlẹ to ṣẹlẹ nibe.

Ṣugbọn ko jọ pe Adajọ Okuwobi ṣetan lati gba ẹbẹ wọn pẹlu bo ṣe ni oun ko gbọdọ ja pẹtẹ ẹsẹ wọn nibẹ.

Leave a Reply